Owe 6:1-5
Owe 6:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌMỌ mi, bi iwọ ba ṣe onigbọwọ fun ọrẹ́ rẹ, bi iwọ ba jẹ́ ẹ̀jẹ́ fun ajeji enia. Bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ dẹkùn fun ọ, bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ mu ọ. Njẹ, sa ṣe eyi, ọmọ mi, ki o si gbà ara rẹ silẹ nigbati iwọ ba bọ si ọwọ ọrẹ́ rẹ; lọ, rẹ ara rẹ silẹ, ki iwọ ki o si tù ọrẹ́ rẹ. Máṣe fi orun fun oju rẹ, tabi õgbe fun ipenpeju rẹ. Gbà ara rẹ bi abo agbọnrin li ọwọ ọdẹ, ati bi ẹiyẹ li ọwọ apẹiyẹ.
Owe 6:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì, tí o bá bọ́ sinu tàkúté tí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ, o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ. Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ là: lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́. Má sùn, má sì tòògbé, gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ, àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.
Owe 6:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn, bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté, Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ: lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀; bẹ aládùúgbò rẹ dáradára Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá. Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.