Owe 5:18-20
Owe 5:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba. Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra?
Owe 5:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun, kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin. Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo, kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà. Kí ló dé, ọmọ mi, tí ìfẹ́ alágbèrè obinrin yóo fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn, tí o óo fi máa dìrọ̀ mọ́ obinrin olobinrin?
Owe 5:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún; kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ. Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkúgbà. Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà, tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?