Owe 5:15-19
Owe 5:15-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ. Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita. Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ. Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba.
Owe 5:15-19 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi; omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu. Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri, bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́, má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀. Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun, kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin. Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo, kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà.
Owe 5:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mu omi láti inú kànga tìrẹ Omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ. Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà? Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé. Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún; kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ. Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkúgbà.