Owe 28:25-28
Owe 28:25-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o ṣe agberaga li aiya, a rú ìja soke, ṣugbọn ẹniti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o mu sanra. Ẹniti o gbẹkẹ le aiya ara rẹ̀, aṣiwère ni; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nfi ọgbọ́n rìn, on li a o gbà la. Ẹniti o ba nfi fun olupọnju kì yio ṣe alaini: ṣugbọn ẹniti o mu oju rẹ̀ kuro, yio gbà egún pupọ. Nigbati enia buburu ba hù, awọn enia a sá pamọ́: ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣegbe, awọn olododo a ma pọ̀ si i.
Owe 28:25-28 Yoruba Bible (YCE)
Olójúkòkòrò eniyan a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ṣe rere. Òmùgọ̀ ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀, ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn yóo là. Ẹni tí ó ta talaka lọ́rẹ kò ní ṣe aláìní, ṣugbọn ẹni tí ó fojú pamọ́ fún wọn, yóo gba ègún. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá parun, olódodo á pọ̀ sí i.
Owe 28:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLúWA yóò gbilẹ̀. Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu. Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún. Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé, àwọn olódodo ń gbilẹ̀ sí i.