Owe 24:1-34

Owe 24:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

IWỌ máṣe ilara si awọn enia buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ lati ba wọn gbe. Nitoriti aiya wọn ngbiro iparun, ète wọn si nsọ̀rọ ìwa-ika. Ọgbọ́n li a fi ikọ ile; oye li a si fi ifi idi rẹ̀ kalẹ. Nipa ìmọ ni iyará fi ikún fun oniruru ọrọ̀ iyebiye ati didùn. Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ. Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun. Ọgbọ́n ga jù aṣiwère lọ: on kì yio yà ẹnu rẹ̀ ni ẹnu-bode. Ẹniti nhùmọ ati ṣe ibi li a o pè li enia ìwa-ika. Ironu wère li ẹ̀ṣẹ; irira ninu enia si li ẹlẹgàn. Bi iwọ ba rẹwẹsi li ọjọ ipọnju, agbara rẹ ko to nkan. Bi iwọ ba fà sẹhin ati gbà awọn ti a wọ́ lọ sinu ikú, ati awọn ti a yàn fun pipa. Ti iwọ si wipe, wò o, awa kò mọ̀ ọ; kò ha jẹ pe ẹniti ndiwọ̀n ọkàn nkiyesi i? ati ẹniti npa ọkàn rẹ mọ́, on li o mọ̀, yio si san a fun enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀. Ọmọ mi, jẹ oyin, nitoriti o dara; ati afara oyin, ti o dùn li ẹnu rẹ: Bẹ̃ni ìmọ ọgbọ́n yio ri si ọkàn rẹ: bi iwọ ba ri i, nigbana ni ère yio wà, a kì yio si ke ireti rẹ kuro. Máṣe ba ni ibuba bi enia buburu, lati gba ibujoko olododo: máṣe fi ibi isimi rẹ̀ ṣe ijẹ. Nitoripe olõtọ a ṣubu nigba meje, a si tun dide: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu sinu ibi. Máṣe yọ̀ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹ ki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsẹ̀: Ki Oluwa ki o má ba ri i, ki o si buru li oju rẹ̀, on a si yi ibinu rẹ̀ pada kuro lori rẹ̀. Máṣe ilara si awọn enia buburu, má si ṣe jowu enia buburu. Nitoripe, ère kì yio si fun enia ibi; fitila enia buburu li a o pa. Ọmọ mi, iwọ bẹ̀ru Oluwa ati ọba: ki iwọ ki o má si ṣe dàpọ mọ awọn ti nṣe ayidayida. Nitoripe wàhala wọn yio dide lojiji, ati iparun awọn mejeji, tali o mọ̀ ọ! Wọnyi pẹlu ni ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n. Kò dara lati ṣe ojuṣãju ni idajọ. Ẹniti o ba wi fun enia buburu pe, olododo ni iwọ; on ni awọn enia yio bú, awọn orilẹ-ède yio si korira rẹ̀. Ṣugbọn awọn ti o ba a wi ni yio ni inu-didùn, ibukún rere yio si bọ̀ sori wọn. Yio dabi ẹniti o ṣe ifẹnukonu: ẹniti o ba ṣe idahùn rere. Mura iṣẹ rẹ silẹ lode, ki o si fi itara tulẹ li oko rẹ; nikẹhin eyi, ki o si kọ́ ile rẹ. Máṣe ẹlẹri si ẹnikeji rẹ lainidi: ki iwọ ki o má si ṣe fi ète rẹ ṣẹ̀tan. Máṣe wipe, bẹ̃li emi o ṣe si i, gẹgẹ bi o ti ṣe si mi: emi o san a fun ọkunrin na gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀. Mo kọja lọ li oko ọlẹ, ati lẹba ọgbà-ajara ẹniti oye kù fun: Si kiyesi i, ẹgún kún bo gbogbo rẹ̀, igbó si bo oju rẹ̀, iganna okuta rẹ̀ si wo lulẹ. Nigbana ni mo ri, mo si fi ọkàn mi si i gidigidi: mo wò o, mo si gbà ẹkọ́. Orun diẹ si i, õgbe diẹ, ikawọkòpọ lati sùn diẹ. Bẹ̃li òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn; ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.

Owe 24:1-34 Yoruba Bible (YCE)

Má ṣe ìlara àwọn ẹni ibi, má sì ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́, nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ìparun, ẹnu wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìkà. Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé, òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kó oniruuru nǹkan ìní dáradára olówó iyebíye kún àwọn yàrá rẹ̀ Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ, ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ. Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun, ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà. Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀, kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ. Ẹni tí ń pète àtiṣe ibi ni a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀, ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn. Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú, a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó. Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀, fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada. Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀, ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i? Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀, àbí kò ní san án fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀? Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn, oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu. Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ, bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la, ìrètí rẹ kò sì ní di asán. Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo, má fọ́ ilé rẹ̀. Nítorí pé bí olódodo bá ṣubú léra léra nígbà meje, yóo tún dìde, ṣugbọn àjálù máa ń bi ẹni ibi ṣubú. Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀, kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ, kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ. Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi, má sì ṣe jowú eniyan burúkú, nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi, a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú. Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba, má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn; nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì, ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá? Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí: Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́. Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè, àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀. Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi, ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn. Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́ dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu. Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta, tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ, lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ. Má jẹ́rìí lòdì sí aládùúgbò rẹ láìnídìí, má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu rẹ jáde. Má sọ pé, “Bí lágbájá ti ṣe sí mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà yóo ṣe sí i, n óo san ẹ̀san ohun tí ó ṣe fún un.” Mo gba ẹ̀gbẹ́ oko ọ̀lẹ kan kọjá, mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹnìkan tí kò lóye. Wò ó! Ẹ̀gún ti hù níbi gbogbo, igbó ti bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀, ọgbà tí ó fi òkúta ṣe yí i ká sì ti wó. Mo ṣe àṣàrò lórí ohun tí mo ṣàkíyèsí, mo sì kọ́ ẹ̀kọ́ lára ohun tí mo rí. Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi, bẹ́ẹ̀ ni òṣì yóo ṣe dé bá ọ bíi kí olè yọ sí eniyan, àìní yóo sì wọlé tọ̀ ọ́ bí ẹni tí ó di ihamọra ogun.

Owe 24:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́; Nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú, ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀. Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀; Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀, ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà: nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀. Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí. Ẹni tí ń pète ibi ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi. Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn. Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó! Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà. Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,” ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n? Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe? Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu. Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo. Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú láti gba ibùjókòó olódodo, má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ; nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde sá á ni, ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀. Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú; nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀. Àìṣe bẹ́ẹ̀ OLúWA yóò rí i yóò sì bínú yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú, nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú. Bẹ̀rù OLúWA àti ọba, ọmọ mi, má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun. Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn, ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá? Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n: láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá: Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre” àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn. Ìdáhùn òtítọ́ dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu. Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára; lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ. Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí, tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ. Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi; Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.” Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ, mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn; ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí; oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè.