Owe 23:22-25
Owe 23:22-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó. Ra otitọ, ki o má si ṣe tà a; ọgbọ́n pẹlu ati ẹkọ́, ati imoye. Baba olododo ni yio yọ̀ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọ́n, yio ni ayọ̀ ninu rẹ̀. Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.
Owe 23:22-25 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ, má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i. Ra òtítọ́, má sì tà á, ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu. Baba olódodo ọmọ yóo láyọ̀ pupọ, inú ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóo dùn. Mú inú baba ati ìyá rẹ dùn, jẹ́ kí ìyá tí ó bí ọ láyọ̀ lórí rẹ.
Owe 23:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á; ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye. Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi: ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀. Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀, sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.