Owe 2:6-9
Owe 2:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori Oluwa ni ifi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ ati oye ti iwá. O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede. O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́. Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere.
Owe 2:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n, ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá. Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́, ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere.
Owe 2:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí OLúWA ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé, ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́, àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.