Owe 19:17-19
Owe 19:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o ṣãnu fun talaka Oluwa li o win; ati iṣeun rẹ̀, yio san a pada fun u. Nà ọmọ rẹ nigbati ireti wà, má si ṣe gbe ọkàn rẹ le ati pa a. Onibinu nla ni yio jiya; nitoripe bi iwọ ba gbà a, sibẹ iwọ o tun ṣe e.
Pín
Kà Owe 19Owe 19:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó ṣe ojurere fún àwọn talaka, OLUWA ni ó ṣe é fún, OLUWA yóo sì san ẹ̀san rẹ̀ fún un. Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ó sì lè gbọ́ ìbáwí, má sì ṣe wá ìparun rẹ̀. Onínúfùfù yóo jìyà inúfùfù rẹ̀, bí o bá gbà á sílẹ̀ lónìí, o níláti tún gbà á sílẹ̀ lọ́la.
Pín
Kà Owe 19Owe 19:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, OLúWA ní ó yá yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe. Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀. Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀ bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.
Pín
Kà Owe 19