Owe 11:9-11
Owe 11:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnu li agabagebe ifi pa aladugbo rẹ̀: ṣugbọn ìmọ li a o fi gbà awọn olododo silẹ. Nigbati o ba nṣe rere fun olododo, ilu a yọ̀: nigbati enia buburu ba ṣegbe, igbe-ayọ̀ a ta. Nipa ibukún aduro-ṣinṣin ilu a gbé lèke: ṣugbọn a bì i ṣubu nipa ẹnu enia buburu.
Owe 11:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máa fi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀. Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo, gbogbo ará ìlú a máa yọ̀, nígbà tí eniyan burúkú bá kú, gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀. Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú.
Owe 11:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà. Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan. Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.