Owe 11:24-26
Owe 11:24-26 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri, sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní, ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́, sibẹsibẹ aláìní ni. Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún, ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀, ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀. Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà.
Owe 11:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní. Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura. Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.
Owe 11:24-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnikan wà ti ntuka, sibẹ o mbi si i, ẹnikan si wà ti nhawọ jù bi o ti yẹ lọ, ṣugbọn kiki si aini ni. Ọkàn iṣore li a o mu sànra; ẹniti o mbomirin ni, ontikararẹ̀ li a o si bomirin pẹlu. Ẹniti o ba dawọ ọkà duro, on li enia o fibu: ṣugbọn ibukún yio wà li ori ẹniti o tà a.