Owe 1:1-7
Owe 1:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli; Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye; Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe; Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu. Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n: Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn. Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́.
Owe 1:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa, kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́, kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn, láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n, òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú, láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n, kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́, kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu. Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́.
Owe 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀. Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè; láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe. Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà. Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe, àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n. Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.