Owe 1:1-33
Owe 1:1-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli; Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye; Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe; Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu. Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n: Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn. Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́. Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ: Nitoripe awọn ni yio ṣe ade ẹwà fun ori rẹ, ati ọṣọ́ yi ọrùn rẹ ka. Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà. Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi. Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati awọn ẹni-diduroṣinṣin bi awọn ti nlọ sinu iho: Awa o ri onirũru ọrọ̀ iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa: Dà ipin rẹ pọ̀ mọ arin wa; jẹ ki gbogbo wa ki a jọ ni àpo kan: Ọmọ mi, máṣe rìn li ọ̀na pẹlu wọn: fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọ̀na wọn. Nitori ti ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ. Nitõtọ, lasan li a nà àwọn silẹ li oju ẹiyẹkẹiyẹ. Awọn wọnyi si ba fun ẹ̀jẹ ara wọn; nwọn lumọ nikọkọ fun ẹmi ara wọn. Bẹ̃ni ọ̀na gbogbo awọn ti nṣe ojukokoro ère; ti ngba ẹmi awọn oluwa ohun na. Ọgbọ́n nkigbe lode; o nfọhùn rẹ̀ ni igboro: O nke ni ibi pataki apejọ, ni gbangba ẹnubode ilu, o sọ ọ̀rọ rẹ̀ wipe, Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọ̀kan ti ẹnyin o fi ma fẹ aimọ̀kan? ati ti awọn ẹlẹgàn yio fi ma ṣe inudidùn ninu ẹ̀gan wọn, ati ti awọn aṣiwere yio fi ma korira ìmọ? Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi i, emi o dà ẹmi mi sinu nyin, emi o fi ọ̀rọ mi hàn fun nyin. Nitori ti emi pè, ti ẹnyin si kọ̀; ti emi nà ọwọ mi, ti ẹnikan kò si kà a si: Ṣugbọn ẹnyin ti ṣá gbogbo ìgbimọ mi tì, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi: Emi pẹlu o rẹrin idãmu nyin; emi o ṣe ẹ̀fẹ nigbati ibẹ̀ru nyin ba de; Nigbati ibẹ̀ru nyin ba de bi ìji, ati idãmu nyin bi afẹyika-ìji; nigbati wahala ati àrodun ba de si nyin. Nigbana ni ẹnyin o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o ṣafẹri mi ni kùtukùtu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi: Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa. Nwọn kò fẹ ìgbimọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi. Nitorina ni nwọn o ṣe ma jẹ ninu ère ìwa ara wọn, nwọn o si kún fun ìmọkimọ wọn. Nitoripe irọra awọn alaimọ̀kan ni yio pa wọn, ati alafia awọn aṣiwere ni yio pa wọn run. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fetisi mi yio ma gbe lailewu, yio si farabalẹ kuro ninu ibẹ̀ru ibi.
Owe 1:1-33 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa, kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́, kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn, láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n, òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú, láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n, kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́, kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu. Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́. Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ, má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ, nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ, ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ. Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà. Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa ká lọ, kí á lọ sápamọ́ láti paniyan, kí á lúgọ de aláìṣẹ̀, jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú, a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó, ilé wa yóo sì kún fún ìkógun. Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa, kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.” Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́, má sì bá wọn rìn, nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí, wọ́n a sì máa yára láti paniyan. Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀, nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni, ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè, ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí. Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí, ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn. Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà, ó ń pariwo láàrin ọjà, ó ń kígbe lórí odi ìlú, ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní, “Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín? Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn, tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀? Ẹ fetí sí ìbáwí mi, n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín, n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín. Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́, mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn, ẹ ti pa gbogbo ìmọ̀ràn mi tì, ẹ kò sì gbọ́ ọ̀kankan ninu ìbáwí mi. Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ín nígbà tí ìdààmú bá dé ba yín, n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà nígbà tí ìpayà bá dé ba yín. Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì, tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle, tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀. Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, ṣugbọn n kò ní dáhùn. Ẹ óo wá mi láìsinmi, ṣugbọn ẹ kò ní rí mi. Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀, ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA. Ẹ kò fẹ́ ìmọ̀ràn mi, ẹ sì kẹ́gàn gbogbo ìbáwí mi. Nítorí náà, ẹ óo jèrè iṣẹ́ yín, ìwà burúkú yín yóo sì di àìsàn si yín lára. Àwọn aláìgbọ́n kú nítorí pé wọn kò gba ẹ̀kọ́ aibikita àwọn òmùgọ̀ ni yóo pa wọ́n run. Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ tèmi, yóo máa wà láìléwu, yóo máa gbé pẹlu ìrọ̀rùn, láìsí ìpayà ibi.”
Owe 1:1-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀. Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè; láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe. Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà. Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe, àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n. Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́. Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀. Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká. Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí; Jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò; A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa; Da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà” Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn; Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀, ní ojú ẹyẹ! Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn. Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́; yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ. Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà; Láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde Ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀: “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó? Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó? Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀? Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni, Ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín kí n sì fi inú mi hàn sí i yín. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn, Níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi, Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín; èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín. Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, Nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀. “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi. Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù OLúWA. Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi, Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run; Ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”