Filp 4:7-9
Filp 4:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu. Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò. Nkan wọnni, ti ẹnyin ti kọ́, ti ẹnyin si ti gbà, ti ẹnyin si ti gbọ́, ti ẹnyin si ti ri lọwọ mi, ẹ mã ṣe wọn: Ọlọrun alafia yio si wà pẹlu nyin.
Filp 4:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Alaafia Ọlọrun, tí ó tayọ òye eniyan yóo pa ọkàn ati èrò yín mọ́ ninu Kristi Jesu. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn. Àwọn ohun tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ẹ bá lọ́wọ́ mi, tí ẹ ti gbọ́ lẹ́nu mi, tí ẹ ti rí ninu ìwà mi, àwọn ni kí ẹ máa ṣe. Ọlọrun alaafia yóo sì wà pẹlu yín.
Filp 4:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu. Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.