Filp 4:15-17
Filp 4:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin papa si mọ̀ pẹlu, ẹnyin ara Filippi, pe li ibẹrẹ ihinrere, nigbati mo kuro ni Makedonia, kò si ijọ kan ti o ba mi ṣe alabapin niti gbigbà ati fifunni, bikoṣe ẹnyin nikanṣoṣo. Nitori ni Tessalonika gidi, ẹnyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ fun aini mi. Kì iṣe nitoriti emi nfẹ ẹ̀bun na: ṣugbọn emi nfẹ eso ti yio mã di pupọ nitori nyin.
Filp 4:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará Filipi mọ̀ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìyìn rere mi, nígbà tí mo kúrò ní Masedonia, kò sí ìjọ kan tí ó bá mi lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ fífúnni lẹ́bùn ati gbígba ẹ̀bùn jọ fúnni àfi ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. Nítorí nígbà tí mo wà ní Tẹsalonika kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan mọ, ó tó ẹẹmeji tí ẹ fi nǹkan ranṣẹ sí mi. Kì í ṣe ẹ̀bùn ni mò ń wá, ṣugbọn mò ń wá ọpọlọpọ èso fún anfaani yín.
Filp 4:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín