Filp 4:12-13
Filp 4:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo mọ̀ bi ã ti iṣe di rirẹ̀-silẹ, mo mọ bi ã ti iṣe di pupọ: li ohunkohun ati li ohun gbogbo mo ti kọ́ aṣiri ati mã jẹ ajẹyó ati lati wà li aijẹ, lati mã ni anijù ati lati ṣe alaini. Emi le ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹniti nfi agbara fun mi.
Filp 4:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Mo mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu àìní, mo sì mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu ọpọlọpọ ọrọ̀. Nípòkípò tí mo bá wà, ninu ohun gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kì báà jẹ́ ninu ebi tabi ayo, ninu ọ̀pọ̀ tabi àìní. Mo lè ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹni tí ó ń fún mi ní agbára.
Filp 4:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.