Filp 3:9-11
Filp 3:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki a si le bá mi ninu rẹ̀, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ́: Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀; Bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú.
Filp 3:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Ati pé kí á lè rí i pé mo wà ninu Jesu ati pé n kò ní òdodo ti ara mi nípa iṣẹ́ Òfin bíkòṣe òdodo nípa igbagbọ. Gbogbo àníyàn ọkàn mi ni pé kí n mọ Kristi ati agbára ajinde rẹ̀, kí èmi náà jẹ ninu irú ìyà tí ó jẹ, kí n sì dàbí rẹ̀ nípa ikú rẹ̀, bí ó bá ṣeéṣe kí n lè dé ipò ajinde ninu òkú.
Filp 3:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀; nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.