Filp 3:7-8
Filp 3:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi. Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi
Filp 3:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ohunkohun tí ó ti jẹ́ èrè fún mi ni mo kà sí àdánù. Mo ka gbogbo nǹkan wọnyi sí àdánù nítorí ohun tí ó ṣe iyebíye jùlọ, èyí ni láti mọ Kristi Jesu Oluwa mi, nítorí ẹni tí mo fi pàdánù ohun gbogbo, tí mo fi kà wọ́n sí ìgbẹ́, kí n lè jèrè Jesu.
Filp 3:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi