Filp 2:1-2
Filp 2:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà, Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan.
Pín
Kà Filp 2Filp 2:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, bí ẹ bá ní ìwúrí kankan ninu Kristi, bí ìfẹ́ rẹ̀ bá fun yín ní ìtùnú, bí ẹ bá ní ìrẹ́pọ̀ ninu Ẹ̀mí, bí ẹ bá ní ojú àánú, ẹ mú kí ayọ̀ mi kún nípa pé kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí ẹ fẹ́ nǹkankan náà, kí ẹ ní inú kan, kí èrò yín sì papọ̀.
Pín
Kà Filp 2Filp 2:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànle nítorí pé ìwọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà, síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà.
Pín
Kà Filp 2