Filp 1:9-11
Filp 1:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eyi si ni mo ngbadura fun pe, ki ifẹ nyin ki o le mã pọ si i siwaju ati siwaju ninu imọ̀ ati imoye gbogbo. Ki ẹnyin ki o le dán ohun ti o yàtọ wò; ki ẹ si jasi olododo ati alaijẹ-ohun-ikọsẹ titi fi di ọjọ Jesu Kristi; Lẹhin igbati ẹ ti kun fun eso ododo lati ọdọ Jesu Kristi, fun ogo ati iyìn Ọlọrun.
Filp 1:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Adura mi ni pé kí ìfẹ́ yín máa gbòòrò sí i, kí ìmọ̀ yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ túbọ̀ máa ní làákàyè sí i, kí ẹ lè mọ àwọn ohun tí ó dára jùlọ. Kí ẹ lè jẹ́ aláìlábùkù, kí ẹ sì wà láìsí ohun ìkùnà kan ní ọjọ́ tí Kristi bá dé. Mo tún gbadura pé kí ẹ lè kún fún èso iṣẹ́ òdodo tí ó ti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wá fún ògo ati ìyìn Ọlọrun.
Filp 1:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi: Lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.