File 1:1-3
File 1:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, onde Kristi Jesu, ati Timotiu arakunrin wa, si Filemoni olufẹ ati alabaṣiṣẹ wa ọwọn, Ati si Affia arabinrin wa, ati si Arkippu ọmọ-ogun ẹgbẹ wa, ati si ìjọ inu ile rẹ: Ore-ọfẹ, ati alafia sí nyin, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.
File 1:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Kristi Jesu, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Filemoni, àyànfẹ́ wa ati alábàáṣiṣẹ́ wa, ati sí Afia, arabinrin wa ati sí Akipu: ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ wa fún Kristi, ati sí ìjọ tí ó wà ninu ilé rẹ̀. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu yín ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi.
File 1:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìhìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa. Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa, sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ: Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.