Num 6:23-27
Num 6:23-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israeli; ki ẹ ma wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́: Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ: Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia. Bayi ni nwọn o fi orukọ mi sara awọn ọmọ Israeli; emi o si busi i fun wọn.
Num 6:23-27 Yoruba Bible (YCE)
kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Báyìí ni ẹ óo máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. ‘Kí OLUWA bukun yín, kí ó sì pa yín mọ́. Kí OLUWA mú kí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí yín lára, kí ó sì ṣàánú fún yín. Kí OLUWA bojúwò yín, kí ó sì fún yín ní alaafia.’ “Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo fi orúkọ mi súre fún àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì bukun wọn.”
Num 6:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé: “ ‘ “Kí OLúWA bùkún un yín Kí ó sì pa yín mọ́. Kí OLúWA kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín. Kí OLúWA bojú wò yín; Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’ “Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Israẹli, Èmi ó sì bùkún wọn.”