Num 27:5-10
Num 27:5-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA. OLUWA si sọ fun Mose pe, Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀. Bi on kò ba si lí ọmọbinrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-ini rẹ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀. Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀
Num 27:5-10 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá bá OLUWA sọ̀rọ̀ nípa wọn, OLUWA sì sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn ọmọbinrin Selofehadi bèèrè tọ́, fún wọn ní ilẹ̀ ìní baba wọn láàrin àwọn eniyan baba wọn. Sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnìkan bá kú láìní ọmọkunrin, àwọn ọmọbinrin rẹ̀ yóo jogún ilẹ̀ ìní rẹ̀. Bí kò bá sì ní ọmọbinrin, ilẹ̀ ìní rẹ̀ yóo jẹ́ ti àwọn arakunrin rẹ̀. Bí kò bá ní arakunrin, kí ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún àwọn arakunrin baba rẹ̀.
Num 27:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú OLúWA. OLúWA sì wí fún un pé, “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ń sọ tọ̀nà. Ogbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀. Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Tí kò bá ní arákùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀.