Num 15:37-40
Num 15:37-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si fi aṣẹ fun wọn ki nwọn ki o ṣe wajawaja si eti aṣọ wọn ni iran-iran wọn, ati ki nwọn ki o si fi ọjábulẹ alaró si wajawaja eti aṣọ na: Yio si ma ṣe bi wajawaja fun nyin, ki ẹnyin ki o le ma wò o, ki ẹ si ma ranti gbogbo ofin OLUWA, ki ẹ si ma ṣe wọn: ki ẹnyin ki o má si ṣe tẹle ìro ọkàn nyin ati oju ara nyin, ti ẹnyin ti ima ṣe àgbere tọ̀ lẹhin: Ki ẹnyin ki o le ma ranti, ki ẹ si ma ṣe ofin mi gbogbo, ki ẹnyin ki o le jẹ́ mimọ́ si Ọlọrun nyin.
Num 15:37-40 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe oko jọnwọnjọnwọn sí etí aṣọ wọn ní ìrandíran wọn; kí wọ́n sì ta okùn aláwọ̀ aró mọ oko jọnwọnjọnwọn kọ̀ọ̀kan. Èyí ni ẹ óo máa wọ̀, tí yóo máa rán yín létí àwọn òfin OLUWA, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́; kí ẹ má fi ìwọ̀ra tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn yín ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú yín. Kí ẹ lè máa ranti àwọn òfin mi, kí ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọrun yín.
Num 15:37-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé, “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan. Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wọ̀ láti lè mú yín rántí gbogbo òfin OLúWA, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín. Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́rọ̀ láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín.