Num 15:17-41
Num 15:17-41 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mò ń mu yín lọ, tí ẹ bá jẹ ninu oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ óo mú ọrẹ wá fún OLUWA. Ẹ mú ọrẹ wá fún OLUWA lára àwọn àkàrà tí ẹ kọ́kọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti ibi ìpakà. Lára àwọn àkàrà tí ẹ bá kọ́kọ́ ṣe ni ẹ óo máa mú wá fi ṣe ọrẹ fún OLUWA ní ìrandíran yín. “Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò pa àwọn òfin wọnyi, tí OLUWA fún Mose mọ́, àní àwọn òfin tí OLUWA tipasẹ̀ Mose fún yín, láti ọjọ́ tí OLUWA ti fún un ní òfin títí lọ, ní ìrandíran yín; bí gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá ṣẹ̀, láìmọ̀, wọn óo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli, a óo sì dáríjì wọ́n nítorí pé àṣìṣe ni; wọ́n sì ti mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá fún OLUWA nítorí àṣìṣe wọn. A óo dáríjì gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí ń gbé ààrin wọn nítorí pé gbogbo wọn ni ó lọ́wọ́ sí àṣìṣe náà. “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣẹ̀ láìmọ̀, yóo fi abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Alufaa yóo ṣe ètùtù niwaju pẹpẹ fún olúwarẹ̀ tí ó ṣe àṣìṣe, a óo sì dáríjì í. Òfin kan náà ni ó wà fún gbogbo àwọn tí o bá ṣẹ̀ láìmọ̀, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin ilẹ̀ Israẹli. “Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́nmọ̀ ṣẹ̀, kò náání OLUWA, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin wọn, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó pẹ̀gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, a óo yọ ọ́ kúrò patapata, ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóo sì wà lórí rẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n rí ọkunrin kan tí ń ṣẹ́gi ní ọjọ́ ìsinmi; àwọn tí wọ́n rí i mú un wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni ati gbogbo ìjọ eniyan. Wọ́n fi sí àhámọ́ nítorí wọn kò tíì mọ ohun tí wọn yóo ṣe sí i. OLUWA sọ fún Mose pé, “Pípa ni kí ẹ pa ọkunrin náà, kí gbogbo ìjọ eniyan sọ ọ́ lókùúta pa lẹ́yìn ibùdó.” Gbogbo ìjọ eniyan bá mú un lọ sẹ́yìn ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe oko jọnwọnjọnwọn sí etí aṣọ wọn ní ìrandíran wọn; kí wọ́n sì ta okùn aláwọ̀ aró mọ oko jọnwọnjọnwọn kọ̀ọ̀kan. Èyí ni ẹ óo máa wọ̀, tí yóo máa rán yín létí àwọn òfin OLUWA, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́; kí ẹ má fi ìwọ̀ra tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn yín ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú yín. Kí ẹ lè máa ranti àwọn òfin mi, kí ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó ko yín jáde wa láti ilẹ̀ Ijipti, láti jẹ́ Ọlọrun yín: Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”
Num 15:17-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ na nibiti emi nmú nyin lọ, Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba njẹ ninu onjẹ ilẹ na, ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA. Ki ẹnyin ki o mú àkara atetekọṣu iyẹfun nyin wá fun ẹbọ igbesọsoke: bi ẹnyin ti ṣe ti ẹbọ igbesọsoke ilẹ ipakà, bẹ̃ni ki ẹnyin gbé e sọ. Ninu atetekọ́ṣu iyẹfun nyin ni ki ẹnyin ki o fi fun OLUWA li ẹbọ igbesọsoke, ni iran-iran nyin. Bi ẹnyin ba si ṣìṣe, ti ẹnyin kò si kiyesi gbogbo ofin wọnyi ti OLUWA ti sọ fun Mose, Ani gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun nyin lati ọwọ́ Mose wá, lati ọjọ́ na ti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati lati isisiyi lọ, ni iran-iran nyin; Yio si ṣe, bi a ba fi aimọ̀ ṣe ohun kan ti ijọ kò mọ̀, ki gbogbo ijọ ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá fun ẹbọ sisun, fun õrùn didùn si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀, gẹgẹ bi ìlana na, ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. Ki alufa ki o si ṣètutu fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, a o si darijì wọn; nitoripe aimọ̀ ni, nwọn si ti mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn niwaju OLUWA, nitori aimọ̀ wọn: A o si darijì gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ati alejò ti iṣe atipo lọdọ wọn; nitoripe gbogbo enia wà li aimọ̀. Bi ọkàn kan ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, nigbana ni ki o mú abo-ewurẹ ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. Ki alufa ki o ṣètutu fun ọkàn na ti o ṣẹ̀, nigbati o ba ṣẹ̀ li aimọ̀ niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun u; a o si darijì i. Ofin kan ni ki ẹnyin ki o ní fun ẹniti o ṣẹ̀ ni aimọ̀, ati fun ẹniti a bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn. Ṣugbọn ọkàn na ti o ba fi ikugbu ṣe ohun kan, iba ṣe ibilẹ tabi alejò, o sọ̀rọbuburu si OLUWA; ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. Nitoriti o gàn ọ̀rọ OLUWA, o si ru ofin rẹ̀; ọkàn na li a o ke kuro patapata, ẹ̀ṣẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. Nigbati awọn ọmọ Israeli wà li aginjù, nwọn ri ọkunrin kan ti nṣẹ́ igi li ọjọ́-isimi. Awọn ti o ri i ti nṣẹ́ igi mú u tọ̀ Mose ati Aaroni wá, ati gbogbo ijọ. Nwọn si há a mọ́ ile-ìde, nitoriti a kò ti isọ bi a o ti ṣe e. OLUWA si sọ fun Mose pe, Pipa li a o pa ọkunrin na: gbogbo ijọ ni yio sọ ọ li okuta pa lẹhin ibudó. Gbogbo ijọ si mú u wá sẹhin ibudó, nwọn si sọ ọ li okuta, on si kú; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si fi aṣẹ fun wọn ki nwọn ki o ṣe wajawaja si eti aṣọ wọn ni iran-iran wọn, ati ki nwọn ki o si fi ọjábulẹ alaró si wajawaja eti aṣọ na: Yio si ma ṣe bi wajawaja fun nyin, ki ẹnyin ki o le ma wò o, ki ẹ si ma ranti gbogbo ofin OLUWA, ki ẹ si ma ṣe wọn: ki ẹnyin ki o má si ṣe tẹle ìro ọkàn nyin ati oju ara nyin, ti ẹnyin ti ima ṣe àgbere tọ̀ lẹhin: Ki ẹnyin ki o le ma ranti, ki ẹ si ma ṣe ofin mi gbogbo, ki ẹnyin ki o le jẹ́ mimọ́ si Ọlọrun nyin. Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.
Num 15:17-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo ń mú yín lọ. Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún OLúWA. Ẹ mú àkàrà wá nínú àkọ́so oúnjẹ yín wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè sí OLúWA, ọrẹ láti inú ilẹ̀ ìpakà yín. Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún OLúWA. “ ‘Bí ẹ bá kùnà láìròtẹ́lẹ̀ láti pa àwọn òfin tí OLúWA fún Mose mọ́: Èyí ni gbogbo òfin tí OLúWA fún yín láti ẹnu Mose láti ọjọ́ tí OLúWA ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀. Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá wáyé láìròtẹ́lẹ̀ láìjẹ́ pé ìjọ ènìyàn mọ̀ sí i, nígbà náà ni kí gbogbo ìjọ ènìyàn mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan wá fún ẹbọ sísun bí òórùn dídùn sí OLúWA, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà, pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù, fun gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, a ó sì dáríjì wọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti mú ọrẹ àfinásun wá fún OLúWA nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀. A ó dárí jí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli àti àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín wọn nítorí pé ní àìròtẹ́lẹ̀ ni wọ́n sẹ ẹ̀ṣẹ̀ náà. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ẹnìkan ló sẹ̀ ní àìròtẹ́lẹ̀, kí ó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Àlùfáà yóò ṣe ètùtù níwájú OLúWA fún ẹni tó ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, tí wọ́n bá ṣe ètùtù fún un, a ó sì dáríjì í. Òfin kan kí ẹ̀yin kí ó ní fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ ní àìmọ̀, àti fún àwọn ẹni tí a bí nínú àwọn ọmọ Israẹli, àti fún àlejò tí ń ṣe àtìpó. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yálà ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ OLúWA, a ó sì gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀ Nítorí pé ẹni náà ti kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLúWA ó sì ti rú òfin rẹ̀, a gbọdọ̀ gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí rẹ̀.’ ” Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà nínú aginjù, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣá igi ní ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn; Wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.” Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókùúta pa, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose. OLúWA sọ fún Mose pé, “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan. Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wọ̀ láti lè mú yín rántí gbogbo òfin OLúWA, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín. Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́rọ̀ láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Ejibiti láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.’ ”