Num 11:4-6
Num 11:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn adalú ọ̀pọ enia ti o wà pẹlu wọn ṣe ifẹkufẹ: awọn ọmọ Israeli pẹlu si tun sọkun wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? Awa ranti ẹja, ti awa ti njẹ ni Egipti li ọfẹ; ati apálà, ati bàra, ati ewebẹ, ati alubọsa, ati eweko: Ṣugbọn nisisiyi ọkàn wa gbẹ: kò sí ohun kan rára, bikọse manna yi niwaju wa.
Num 11:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn, pé àwọn kò rí ẹran jẹ bí ìgbà tí àwọn wà ní Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún àìrẹ́ran jẹ. Wọ́n ń sọ pé, “Ó mà ṣe o, a kò rí ẹran jẹ! Ní Ijipti, à ń jẹ ẹja ati apálà, ẹ̀gúsí, ewébẹ̀, alubọsa ati galiki. Ṣugbọn nisinsinyii, a kò lókun ninu mọ́, kò sí ohun tí a rí jẹ bíkòṣe mana yìí nìkan lojoojumọ.”
Num 11:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrín àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fi ìtara béèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Israẹli náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí! Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Ejibiti, apálà, bàrà, ewébẹ̀, àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi manna nìkan tí a rí yìí!”