Neh 9:1-38
Neh 9:1-38 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi, awọn ọmọ Israeli pejọ ninu àwẹ ati aṣọ ọ̀fọ, ati erupẹ lori wọn. Awọn iru-ọmọ Israeli si ya ara wọn kuro ninu awọn ọmọ alejo, nwọn si duro, nwọn jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati aiṣedede awọn baba wọn. Nwọn si dide duro ni ipò wọn, nwọn si fi idamẹrin ọjọ kà ninu iwe ofin Oluwa Ọlọrun wọn; nwọn si fi idamẹrin jẹwọ, nwọn si sìn Oluwa Ọlọrun wọn. Nigbana ni Jeṣua, ati Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani ati Kenani duro lori pẹtẹsì awọn ọmọ Lefi, nwọn si fi ohun rara kigbe si Oluwa Ọlọrun wọn. Awọn ọmọ Lefi, Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣabaiah, Ṣerebiah, Hodijah, Sebaniah, ati Pelaniah, si wipe: Ẹ dide, ki ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin lai ati lailai: ibukun si ni fun orukọ rẹ ti o li ogo, ti o ga jù gbogbo ibukun ati iyìn lọ. Iwọ, ani iwọ nikanṣoṣo li Oluwa; iwọ li o ti dá ọrun, ọrun awọn ọrun pẹlu gbogbo ogun wọn, aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ̀ ninu rẹ̀, iwọ si pa gbogbo wọn mọ́ lãyè, ogun ọrun si nsìn ọ. Iwọ ni Oluwa Ọlọrun, ti o ti yan Abramu, ti o si mu u jade lati Uri ti Kaldea wá, iwọ si sọ orukọ rẹ̀ ni Abrahamu; Iwọ si ri pe ọkàn rẹ̀ jẹ olõtọ niwaju rẹ, iwọ si ba a dá majẹmu lati fi ilẹ awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Amori, ati awọn ara Perisi, ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Girgasi fun u, lati fi fun iru-ọmọ rẹ̀, iwọ si ti mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ; nitori olododo ni iwọ: Iwọ si ri ipọnju awọn baba wa ni Egipti, o si gbọ́ igbe wọn lẹba Okun Pupa; O si fi ami, ati iṣẹ-iyanu hàn li ara Farao, ati li ara gbogbo iranṣẹ rẹ̀, ati li ara gbogbo enia ilẹ rẹ̀: nitori iwọ mọ̀ pe, nwọn hu ìwa igberaga si wọn. Iwọ si fi orukọ fun ara rẹ bi ti oni yi. Iwọ si ti pin okun niwaju wọn, nwọn si la arin okun ja li ori ilẹ gbigbẹ; iwọ sọ awọn oninunibini wọn sinu ibú, bi okuta sinu omi lile. Iwọ si fi ọwọ̀n awọ-sanma ṣe amọ̀na wọn li ọsan, ati li oru, ọwọ̀n iná, lati fun wọn ni imọlẹ li ọ̀na ninu eyiti nwọn o rin. Iwọ si sọkalẹ wá si ori òke Sinai, o si bá wọn sọ̀rọ lati ọrun wá, o fun wọn ni idajọ titọ, ofin otitọ, ilana ati ofin rere. Iwọ si mu ọjọ isimi mimọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, o si paṣẹ ẹkọ́, ilana, ati ofin fun wọn, nipa ọwọ Mose iranṣẹ rẹ. O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn. Ṣugbọn awọn ati awọn baba wa hu ìwa igberaga, nwọn si mu ọrùn wọn le, nwọn kò si gba ofin rẹ gbọ́. Nwọn si kọ̀ lati gbọràn, bẹ̃ni nwọn kò ranti iṣẹ iyanu ti iwọ ṣe li ãrin wọn; ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, ninu ìṣọtẹ wọn, nwọn yan olori lati pada si oko-ẹrú wọn: ṣugbọn iwọ li Ọlọrun ti o mura lati dariji, olore ọfẹ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pipọ̀, o kò si kọ̀ wọn silẹ. Nitõtọ nigbati nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu didà, ti nwọn si wipe, Eyi li Ọlọrun rẹ ti o mu ọ gòke ti Egipti jade wá, nwọn si ṣe imunibinu nla. Ṣugbọn iwọ, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, kò kọ̀ wọn silẹ li aginju, ọwọ̀n kũkũ kò kuro lọdọ wọn lojojumọ lati ṣe amọna wọn, bẹ̃ si li ọwọ̀n iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru li ọ̀na ti nwọn iba rìn. Iwọ fun wọn li ẹmi rere rẹ pẹlu lati kọ́ wọn, iwọ kò si gba manna rẹ kuro li ẹnu wọn, iwọ si fun wọn li omi fun orungbẹ wọn. Nitotọ, ogoji ọdun ni iwọ fi bọ́ wọn li aginju, nwọn kò si ṣe alaini; aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ wọn kò si wú. Pẹlupẹlu iwọ fi ijọba ati orilẹ-ède fun wọn, o si pin wọn si ìha gbogbo, bẹ̃ni nwọn jogun ilẹ Sihoni, ati ilẹ ọba Heṣboni, ati ilẹ Ogu, ọba Baṣani. Awọn ọmọ wọn pẹlu ni iwọ sọ di pipọ bi irawọ ọrun, o si mu wọn wá ilẹ na sipa eyiti o ti leri fun awọn baba wọn pe: ki nwọn lọ sinu rẹ̀ lati gbà a. Bẹ̃li awọn ọmọ na wọ inu rẹ̀ lọ, nwọn si gbà ilẹ na, iwọ si tẹ ori awọn ara ilẹ na ba niwaju wọn, awọn ara Kenaani, o si fi wọn le ọwọ wọn, pẹlu ọba wọn, ati awọn enia ilẹ na, ki nwọn ki o le fi wọn ṣe bi o ti wù wọn. Nwọn si gbà ilu alagbara, ati ilẹ ọlọra, nwọn si gbà ilẹ ti o kún fun ohun rere, kanga, ọgba-ajara, ọgba-olifi, ati igi eleso, li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni nwọ́n jẹ, nwọn si yo, nwọ́n sanra, nwọn si ni inu-didùn ninu ore rẹ nla. Ṣugbọn nwọn ṣe alaigbọràn, nwọn si ṣọ̀tẹ si ọ, nwọn si gbe ofin rẹ sọ si ẹ̀hin wọn, nwọn si pa awọn woli rẹ ti nsọ fun wọn lati yipada si ọ, nwọn si ṣe imunibinu nla. Nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ti o pọn wọn loju, ati li akoko ipọnju wọn, nigbati nwọn kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá; ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, iwọ fun wọn li olugbala, ti nwọn gbà wọn kuro lọwọ awọn ọta wọn. Ṣugbọn li ẹhin ti nwọn ni isimi, nwọn si tun ṣe buburu niwaju rẹ: nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, tobẹ̃ ti nwọn jọba li ori wọn: ṣugbọn nigbati nwọn pada, ti nwọn si kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá, ọ̀pọlọpọ ìgba ni iwọ si gbà wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ. Iwọ si jẹri gbè wọn ki iwọ ki o le tun mu wọn wá sinu ofin rẹ, ṣugbọn nwọn hu ìwa igberaga, nwọn kò si fi eti si ofin rẹ, nwọn si ṣẹ̀ si idajọ rẹ (eyiti bi enia ba ṣe on o yè ninu wọn), nwọn si gún èjika, nwọn mu ọrùn wọn le, nwọn kò si fẹ igbọ́. Sibẹ ọ̀pọlọpọ ọdun ni iwọ fi mu suru fun wọn ti o si fi ẹmi rẹ jẹri gbè wọn ninu awọn woli rẹ: sibẹ̀ nwọn kò fi eti silẹ: nitorina ni iwọ ṣe fi wọn le ọwọ awọn enia ilẹ wọnni. Ṣugbọn nitori ãnu rẹ nla iwọ kò run wọn patapata, bẹ̃ni iwọ kò kọ̀ wọn silẹ; nitori iwọ li Ọlọrun olore-ọfẹ ati alãnu. Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, Ọlọrun ti o tobi, ti o li agbara, ti o si li ẹ̀ru, ẹniti npa majẹmu ati ãnu mọ, má jẹ ki gbogbo iyọnu na dabi ohun kekere niwaju rẹ, o de bá wa, awọn ọba wa, awọn ijoye wa, ati awọn alufa wa, ati awọn woli wa, ati awọn baba wa, ati gbogbo awọn enia rẹ lati akoko ọba Assiria wá, titi o fi di oni yi. Sibẹ, iwọ ṣe olododo ninu ohun gbogbo ti o de ba wa, iwọ si ti ṣe otitọ, ṣugbọn awa ti ṣe buburu: Awọn ọba wa, awọn ijoye wa, awọn alufa wa, ati awọn baba wa, kò pa ofin rẹ mọ, bẹ̃ni nwọn kò fi eti si aṣẹ rẹ, ati ẹri rẹ, ti iwọ fi jẹri gbè wọn. Nitori ti nwọn kò sin ọ ninu ijọba wọn, ati ninu ore rẹ nla ti iwọ fi fun wọn, ati ninu ilẹ nla ati ọlọra ti o fi si iwaju wọn, bẹ̃ni nwọn kò pada kuro ninu iṣẹ buburu wọn. Kiyesi i, ẹrú li awa iṣe li oni yi, ati ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa lati ma jẹ eso rẹ̀, ati ire rẹ̀, kiyesi i, awa jẹ ẹrú ninu rẹ̀. Ilẹ na si mu ohun ọ̀pọlọpọ wá fun awọn ọba, ti iwọ ti fi ṣe olori wa nitori ẹ̀ṣẹ wa: nwọn ni aṣẹ lori ara wa pẹlu, ati lori ẹran-nla wa, bi o ti wù wọn, awa si wà ninu wàhala nla. Ati nitori gbogbo eyi awa dá majẹmu ti o daju, a si kọwe rẹ̀; awọn ìjoye wa, awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa si fi èdidi di i.
Neh 9:1-38 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọ pọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì ku eruku sí orí wọn. Wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn àlejò, wọ́n dìde dúró, wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn. Wọ́n dúró ní ààyè wọn, wọ́n sì ka ìwé òfin OLUWA Ọlọrun wọn fún bíi wakati mẹta lọ́jọ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún nǹkan bíi wakati mẹta, wọ́n sì sin OLUWA Ọlọrun wọn. Jeṣua, Bani, ati Kadimieli, Ṣebanaya, Bunni, Ṣerebaya, Bani, ati Kenani dúró lórí pèpéle àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì gbadura sókè sí OLUWA Ọlọrun wọn. Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Kadimieli, Bani, Haṣabineya, Ṣerebaya, Hodaya, Ṣebanaya ati Petahaya, pè wọ́n pé, “Ẹ dìde dúró kí ẹ sì yin OLUWA Ọlọrun yín lae ati laelae. Ìyìn ni fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo, tí ó ga ju gbogbo ibukun ati ìyìn lọ.” Ẹsira ní: “Ìwọ nìkan ni OLUWA, ìwọ ni o dá ọ̀run, àní, ọ̀run tí ó ga jùlọ, ati gbogbo àwọn ìràwọ̀ tí ó wà lójú ọ̀run, ìwọ ni o dá ilé ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, ati àwọn òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. Ìwọ ni o mú kí gbogbo wọn wà láàyè, ìwọ sì ni àwọn ogun ọ̀run ń sìn. Ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun, tí ó yan Abramu, tí o mú un jáde wá láti ìlú Uri tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea, tí o sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Abrahamu. O rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí ọ, O sì bá a dá majẹmu láti fún àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Jebusi ati ti àwọn ará Girigaṣi, o sì ti mú ìlérí náà ṣẹ nítorí pé olódodo ni ọ́. “O ti rí ìpọ́njú àwọn baba wa ní ilẹ̀ Ijipti o sì gbọ́ igbe wọn ní etí Òkun Pupa, o sì ṣe iṣẹ́ àmì ati ìyanu, o fi jẹ Farao níyà ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà, nítorí pé wọ́n hùwà ìgbéraga sí àwọn baba wa, o gbé orúkọ ara rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ó ti wà lónìí. O pín òkun sí meji níwájú wọn, kí wọ́n lè gba ààrin rẹ̀ kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, o sì sọ àwọn tí wọn ń lé wọn lọ sinu ibú bí ẹni sọ òkúta sinu omi. Ò ń fi ọ̀wọ̀n ìkùukùu darí wọn lọ́sàn-án, o sì ń fi ọ̀wọ̀n iná darí wọn lóru, ò ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n rìn. O sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, o sì fún wọn ní ìlànà ati ìdájọ́ tí ó tọ̀nà ati àwọn òfin tòótọ́, O kọ́ wọn láti máa pa ọjọ́ ìsinmi rẹ mọ́, o sì tún pèsè ẹ̀kọ́, ìlànà, ati òfin fún wọn láti ọwọ́ Mose iranṣẹ rẹ. O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n, o sì ń fún wọn ní omi mu láti inú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n. O ní kí wọ́n lọ gba ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí láti fún wọn bí ohun ìní wọn. “Àwọn ati àwọn baba wa hùwà ìgbéraga, wọn ṣe orí kunkun, wọn kò sì pa òfin náà mọ́. Wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì ranti àwọn ohun ìyanu tí o ṣe láàrin wọn, ṣugbọn wọ́n ṣoríkunkun, wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pada sinu ìgbèkùn wọn ní Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun tíí dáríjì ni ni Ọ́, olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú sì ni ọ́, o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kìí yẹ̀, nítorí náà o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n tilẹ̀ yá ère ọmọ mààlúù, tí wọn ń sọ pé, ‘Ọlọrun wọn tí ó kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni,’ tí wọ́n sì ń hu ìwà ìmúnibínú, nítorí àánú rẹ, o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó ń tọ́ wọn sọ́nà kò fìgbà kan kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀n iná kò sì fi wọ́n sílẹ̀ lóru. Ó ń tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lálẹ́, láti máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa rìn. O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti máa kọ́ wọn, o kò dá mana rẹ dúró, o fi ń bọ́ wọn. O sì ń fún wọn ni omi mu nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹ wọ́n. Ogoji ọdún ni o fi bọ́ wọn ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì ṣe àìní ohunkohun, aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú. O gba ọpọlọpọ ìjọba ati ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fún wọn, o sì fi ibi gbogbo fún wọn. Wọ́n gba ilẹ̀ ìní Sihoni, ọba Heṣiboni, ati ti Ogu, ọba Baṣani. O jẹ́ kí ìrandíran wọn pọ̀ sí i bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, o sì kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wọn pé wọn yóo lọ gbà. Àwọn ọmọ wọn lọ sí ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á, o ṣẹgun àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, o sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, àtàwọn, àtọba wọn, àtilẹ̀ wọn, kí àwọn ọmọ Israẹli lè ṣe wọ́n bí wọ́n bá ti fẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo àwọn ìlú olódi ati ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, wọ́n sì gba ilé tí ó kún fún ọpọlọpọ àwọn nǹkan dáradára, ati kànga, ọgbà àjàrà, igi olifi ati ọpọlọpọ igi eléso, nítorí náà wọ́n jẹ wọ́n yó, wọ́n sanra, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ninu oore ńlá rẹ. “Ṣugbọn, wọ́n ṣe àìgbọràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wọ́n pa àwọn òfin rẹ tì sí apákan, wọ́n pa àwọn wolii rẹ tí wọ́n ti ń kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yipada sí ọ, wọ́n sì ń hùwà àbùkù sí ọ. Nítorí náà, o fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá sì jẹ wọ́n níyà, nígbà tí ìyà ń jẹ wọ́n, wọ́n ké pè ọ́, o sì gbọ́ igbe wọn lọ́run, gẹ́gẹ́ bí àánú rẹ ńlá, o gbé àwọn kan dìde bíi olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Ṣugbọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ní ìsinmi tán, wọ́n tún ṣe nǹkan burúkú níwájú rẹ, o sì tún fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn. Sibẹsibẹ, nígbà tí wọ́n ronupiwada tí wọ́n sì gbadura sí ọ, o gbọ́ lọ́run, lọpọlọpọ ìgbà ni o sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ. Ò sì máa kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n lè yipada sí òfin rẹ. Sibẹ wọn a máa hùwà ìgbéraga, wọn kìí sìí pa òfin rẹ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọn a máa ṣẹ̀ sí òfin rẹ, tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá pamọ́, ẹni náà yóo yè. Ṣugbọn wọn ń dágunlá, wọ́n ń ṣe orí kunkun, wọn kò sì gbọ́ràn. Ọpọlọpọ ọdún ni o fi mú sùúrù pẹlu wọ́n, tí o sì ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ, láti ẹnu àwọn wolii rẹ, sibẹ wọn kò fetí sílẹ̀. Nítorí náà ni o ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ṣẹgun wọn. Ṣugbọn nítorí àánú rẹ ńlá, o kò jẹ́ kí wọ́n parun patapata, bẹ́ẹ̀ ni o kò pa wọ́n tì, nítorí pé Ọlọrun olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni ọ́. “Nítorí náà, nisinsinyii Ọlọrun wa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, Ọlọrun tí ó bani lẹ́rù, Ọlọrun tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, má fi ojú kékeré wo gbogbo ìnira tí ó dé bá wa yìí, ati èyí tí ó dé bá àwọn ọba wa, ati àwọn olórí wa, àwọn alufaa wa, ati àwọn wolii wa, àwọn baba wa, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ, láti ìgbà àwọn ọba Asiria títí di ìsinsìnyìí. Sibẹ, o jàre gbogbo ohun tí ó dé bá wa yìí, nítorí pé o ṣe olóòótọ́ sí wa, àwa ni a hùwà burúkú sí ọ. Àwọn ọba wa, ati àwọn ìjòyè wa, àwọn alufaa wa ati àwọn baba wa kọ̀, wọn kò pa òfin rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ, wọn kò sì gbọ́ ìkìlọ̀ rẹ. Pẹlu, bí àwọn nǹkan rere tí o fún wọn ti pọ̀ tó, lórí ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì dára tí o fún wọn. Wọn kò sìn ọ́ ní agbègbè ìjọba wọn, ati ninu oore nla rẹ tí o fun wọn, àní ninu ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú nla tí o bùn wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú wọn. Wò ó ẹrú ni wá lónìí lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa pé kí wọ́n máa gbádùn àwọn èso inú rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára ibẹ̀. Wò ó, a ti di ẹrú lórí ilẹ̀ náà. Àwọn ọrọ̀ inú rẹ̀ sì di ti àwọn ọba tí wọn ń mú wa sìn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, wọ́n ń lo agbára lórí wa ati lórí àwọn mààlúù wa bí ó ṣe wù wọ́n, a sì wà ninu ìpọ́njú ńlá.” Nítorí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọnyi, a dá majẹmu, a sì kọ ọ́ sílẹ̀, àwọn ìjòyè wa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa fi ọwọ́ sí i, wọ́n sì fi èdìdì dì í.
Neh 9:1-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọpọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn. Àwọn ọkùnrin Israẹli sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú gbogbo àwọn àjèjì. Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn. Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin OLúWA Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní sí sin OLúWA Ọlọ́run wọn. Nígbà náà ni Jeṣua, àti Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani àti Kenaani gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì fi ohùn rara kígbe sí OLúWA Ọlọ́run wọn Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣbneiah, Ṣerebiah, Hodiah, Ṣebaniah àti Petahiah—wí pé: “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún OLúWA Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.” “Ìbùkún ni fún orúkọ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ. Ìwọ nìkan ni OLúWA. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́. “Ìwọ ni OLúWA Ọlọ́run, tí ó yan Abramu tí ó sì mú u jáde láti Uri ti Kaldea, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Abrahamu. Ìwọ sì rí í pé ọkàn rẹ̀ jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ, ìwọ sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú u rẹ̀ láti fi ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, Hiti, Amori, Peresi, Jebusi àti Girgaṣi fún irú àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ ti pa ìpinnu rẹ̀ mọ́ nítorí tí ìwọ jẹ́ olódodo. “Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Ejibiti; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun pupa. Ìwọ rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí Farao, sí gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ẹ rẹ̀, nítorí ìwọ mọ ìwà ìgbéraga tí àwọn ará Ejibiti hù sí wọn. Ìwọ ra orúkọ fún ara à rẹ, èyí tí ó sì wà títí di òní yìí. Ìwọ pín Òkun níwájú wọn, nítorí kí wọn lè kọjá ní ìyàngbẹ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ sọ àwọn tí ń lépa wọn sínú ibú, bí òkúta sínú omi ńlá. Ní ọ̀sán ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn àwọsánmọ̀ àti ní òru ni ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà. “Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Sinai; ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára. Ìwọ mú ọjọ́ ìsinmi rẹ mímọ́ di mí mọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òǹgbẹ, o fún wọn ní omi láti inú àpáta; o sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn nípa ìgbọ́wọ́sókè. “Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńlá wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ. Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, Nítòótọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù dídá, tí wọ́n sì wí pé, ‘Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Ejibiti wá; tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì’. “Nítorí àánú ńlá rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní aginjù. Ní ọ̀sán ọ̀wọn ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀wọ́n iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn. Ìwọ fi ẹ̀mí rere rẹ fún wọn láti kọ́ wọn. Ìwọ kò dá manna rẹ dúró ní ẹnu wọn, ó sì fún wọn ní omi fún òǹgbẹ. Fún ogójì ọdún ni ìwọ fi bọ́ wọn ní aginjù; wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wọn kò wú. “Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Sihoni ará a Heṣboni àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani. Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀ Àwọn ọkùnrin wọn wọ inú rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn ará a Kenaani, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájú wọn; ó fi àwọn ará a Kenaani lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n. Wọ́n gba àwọn ìlú olódi àti ilẹ̀ ọlọ́ràá; wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kànga tí a ti gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà, àwọn ọgbà olifi àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáradára; wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ “Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì se ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì. Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì túnṣe búburú lójú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè jẹ ọba lórí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà. “Ìwọ kìlọ̀ fún wọn láti padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n ṣẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olórí kunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú. “Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojú rẹ—ìnira tí ó ti wá sórí wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Asiria wá títí di òní. Ìwọ jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa; ìwọ sì ti ṣe òtítọ́, nígbà tí a bá ṣe búburú. Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ; wọn kò fetísílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn. Àní nígbà tí wọ́n wà nínú ìjọba wọn, tí wọ́n ń gbádùn oore ńlá tí ìwọ fi fún wọn, ní ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì lọ́ràá, wọn kò sìn ọ́ tàbí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn. “Ṣùgbọ́n wò ó, àwa jẹ́ ẹrú lónìí, àwa jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ tí ìwọ fún àwọn baba ńlá wa, nítorí kí wọn bá máa jẹ èso rẹ̀ àti ìre mìíràn tí ó mú jáde. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba tí ó fi ṣe olórí wa. Wọ́n ń ṣe àkóso lórí wa àti lórí ẹran wa bí ó ti wù wọ́n, àwa sì wà nínú ìpọ́njú ńlá. “Nítorí gbogbo èyí, a ń ṣe àdéhùn tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé, àwọn olórí ọmọ Lefi àwọn àlùfáà sì fi èdìdì dì í.”