Neh 8:6-17

Neh 8:6-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Esra si fi ibukun fun Oluwa Ọlọrun, ti o tobi. Gbogbo enia si dahun pe, Amin, Amin! pẹlu gbigbe ọwọ wọn soke: nwọn si tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn Oluwa ni idojubòlẹ̀. Jeṣua pẹlu ati Bani, ati Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodijah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani, Pelaiah, ati awọn ọmọ Lefi, mu ki ofin ye awọn enia: awọn enia si duro ni ipò wọn. Bẹ̃ni nwọn kà ninu iwe ofin Ọlọrun ketekete, nwọn tumọ rẹ̀, nwọn si mu ki iwe kikà na ye wọn. Ati Nehemiah ti iṣe bãlẹ, ati Esra alufa, akọwe, ati awọn ọmọ Lefi, ti o kọ́ awọn enia wi fun gbogbo enia pe, Ọjọ yi jẹ mimọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin; ẹ má ṣọ̀fọ ki ẹ má si sọkún. Nitori gbogbo awọn enia sọkún, nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ ofin. Nigbana ni o wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ jẹ ọ̀ra ki ẹ si mu ohun didùn, ki ẹ si fi apakan ipin ranṣẹ si awọn ti a kò pèse fun: nitori mimọ́ ni ọjọ yi fun Oluwa: ẹ máṣe banujẹ; nitori ayọ̀ Oluwa on li agbàra nyin. Bẹ̃ni awọn ọmọ Lefi mu gbogbo enia dakẹ jẹ, wipe, ẹ dakẹ, nitori mimọ́ ni ọjọ yi; ẹ má si ṣe banujẹ. Gbogbo awọn enia lọ lati jẹ ati lati mu ati lati fi ipin ranṣẹ, ati lati yọ ayọ̀ nla, nitoriti ọ̀rọ ti a sọ fun wọn ye wọn. Li ọjọ keji awọn olori awọn baba gbogbo awọn enia, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pejọ si ọdọ Esra akọwe, ki o le fi ọ̀rọ ofin ye wọn. Nwọn si ri a kọ sinu iwe-ofin, ti Oluwa ti pa li aṣẹ nipa ọwọ Mose pe, ki awọn ọmọ Israeli gbe inu agọ ni àse oṣu keje: Pe, ki nwọn funrere, ki nwọn kede ni gbogbo ilu wọn, ati ni Jerusalemu, wipe, Ẹ jade lọ si òke, ki ẹ si mu ẹka igi olifi, ẹka igi pine, ati ẹka igi matili (myrtle) imọ ọpẹ, ati ẹka igi ti o tobi, lati ṣe agọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ. Bẹ̃ni awọn enia na jade lọ, nwọn si mu wọn wá, nwọn pa agọ fun ara wọn, olukuluku lori orule ile rẹ̀, ati li àgbala wọn, ati li àgbala ile Ọlọrun, ati ni ita ẹnu-bode omi, ati ni ita ẹnu-bode Efraimu. Gbogbo ijọ enia ninu awọn ti o pada bọ̀ lati oko-ẹrú si pa agọ, nwọn si gbe abẹ awọn agọ na: nitori lati akokò Joṣua ọmọ Nuni wá, titi di ọjọ na awọn ọmọ Israeli kò ṣe bẹ̃. Ayọ̀ nlanla si wà.

Neh 8:6-17 Yoruba Bible (YCE)

Ẹsira yin OLUWA, Ọlọrun, tí ó tóbi, gbogbo àwọn eniyan náà gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n dáhùn pé “Amin, Amin,” wọ́n tẹríba, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Bani, Ṣerebaya, Jamini, Akubu, Ṣabetai, Hodaya, Maaseaya, Kelita, Asaraya, Josabadi, Hanani, ati Pelaaya ni wọ́n ń túmọ̀ àwọn òfin náà tí wọ́n sì ń ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan wọn, gbogbo àwọn eniyan dúró ní ààyè wọn. Wọ́n ka òfin Ọlọrun ninu ìwé náà ketekete, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan, ó sì yé wọn. Nehemaya tí ó jẹ́ gomina, ati Ẹsira, alufaa ati akọ̀wé, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n kọ́ àwọn eniyan náà sọ fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ má banújẹ́ tabi kí ẹ sọkún.” Nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n ń sọkún nígbà tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ inú òfin náà. Nehemaya bá sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ, ẹ jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ mu waini dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ranṣẹ sí àwọn tí wọn kò bá ní, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA wa, ẹ má sì banújẹ́, nítorí pé ayọ̀ OLUWA ni agbára yín.” Àwọn ọmọ Lefi rẹ àwọn eniyan náà lẹ́kún, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní, ẹ má bọkàn jẹ́.” Gbogbo àwọn eniyan náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì fi oúnjẹ ati ohun mímu ranṣẹ sí àwọn eniyan wọn, wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá nítorí pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn. Ní ọjọ́ keji, àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, péjọ sọ́dọ̀ Ẹsira, akọ̀wé, kí ó lè la ọ̀rọ̀ òfin náà yé wọn. Wọ́n rí i kà ninu òfin tí OLUWA fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ̀dún oṣù keje, ati pé kí wọ́n kéde rẹ̀ ní gbogbo àwọn ìlú wọn ati ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ lọ sí orí àwọn òkè, kí ẹ sì mú àwọn ẹ̀ka igi olifi wá, ati ti paini, ati ti mitili, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka àwọn igi mìíràn láti fi pàgọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀.” Àwọn eniyan náà jáde, wọ́n sì lọ wá imọ̀ ọ̀pẹ ati ẹ̀ka igi wá, wọ́n sì pàgọ́ fún ara wọn, kaluku pàgọ́ sí orí ilé, ati sí àgbàlá ilé wọn ati sí àgbàlá ilé Ọlọrun pẹlu, wọ́n pàgọ́ sí ìta Ẹnubodè Omi ati sí ìta Ẹnubodè Efuraimu. Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá.

Neh 8:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Esra yin OLúWA, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin OLúWA ní ìdojúbolẹ̀. Àwọn Lefi—Jeṣua, Bani, Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodiah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani àti Pelaiah—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀. Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké. Nígbà náà ni Nehemiah tí ó jẹ́ baálẹ̀, Esra àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Lefi tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún OLúWA Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún” Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sọkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà. Nehemiah wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ OLúWA ni agbára yín.” Àwọn ọmọ Lefi mú kí gbogbo ènìyàn dákẹ́ jẹ́, wọ́n wí pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí mímọ́ ni ọjọ́ yìí. Ẹ má ṣe banújẹ́.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn lọ láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì fi ìpín oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá, nítorí báyìí àwọn òfin tí a sọ di mímọ́ fun wọn ti yé wọn. Ní ọjọ́ kejì oṣù náà, àwọn olórí, gbogbo ìdílé, àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, péjọ sọ́dọ̀ Esra akọ̀wé, wọ́n fi ara balẹ̀ láti fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ òfin. Wọ́n ri ní àkọsílẹ̀ nínú ìwé òfin, èyí tí OLúWA ti pa ní àṣẹ nípasẹ̀ Mose, kí àwọn ọmọ Israẹli gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ àgọ́ oṣù keje àti kí wọn kéde ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tàn án kálẹ̀ ní gbogbo ìlú wọn àti ní Jerusalẹmu: “Ẹ jáde lọ sí ìlú olókè, kí ẹ mú àwọn ẹ̀ka inú olifi àti ẹ̀ka igi olifi igbó, àti láti inú maritili, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn igi tí ó léwé dáradára wá, láti ṣe àgọ́”—gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn jáde lọ, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀ka wá, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn sí orí òrùlé ara wọn, ní àgbàlá wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run àti ní ìta gbangba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè omi àti èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè Efraimu. Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n padà láti ìgbèkùn kọ́ àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú wọn. Láti ọjọ́ Jeṣua ọmọ Nuni títí di ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli kò tí ì ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ bí irú èyí. Ayọ̀ ọ wọn sì pọ̀.