Neh 6:15-19
Neh 6:15-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃li a pari odi na li ọjọ kẹ̃dọgbọn oṣù Eluli, ni ọjọ mejilelãdọta. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọta wa gbọ́, gbogbo awọn keferi àgbegbe wa si bẹ̀ru, nwọn si rẹ̀wẹsi pupọ li oju ara wọn, nitori nwọn woye pe, lati ọwọ Ọlọrun wá li a ti ṣe iṣẹ wọnyi. Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, awọn ijòye Juda ran iwe pupọ si Tobiah, iwe Tobiah si de ọdọ wọn. Nitori ọ̀pọlọpọ ni Juda ti ba a mulẹ nitori ti o jẹ ana Sekaniah ọmọ Ara; ọmọ rẹ̀ Johanani si ti fẹ ọmọ Meṣullamu, ọmọ Berekiah. Nwọn sọ̀rọ rere rẹ̀ pẹlu niwaju mi, nwọn si sọ ọ̀rọ mi fun u. Tobiah rán iwe lati da aiya já mi.

Neh 6:15-19 Yoruba Bible (YCE)
A mọ odi náà parí ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù Eluli. Ó gbà wá ní ọjọ́ mejilelaadọta. Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe. Ati pé àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ lẹta ranṣẹ sí Tobaya ní gbogbo àkókò yìí, Tobaya náà sì ń désì pada sí wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ àwọn ará Juda ni wọ́n ti bá a dá majẹmu, nítorí àna Ṣekanaya ọmọ Ara ni: ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Jehohanani, ló fẹ́ ọmọbinrin Meṣulamu, ọmọ Berekaya. Wọn a máa sọ gbogbo nǹkan dáradára tí ó ń ṣe lójú mi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn a máa sọ ọ̀rọ̀ témi náà bá sọ fún un. Tobaya kò sì dẹ́kun ati máa kọ lẹta sí mi láti dẹ́rù bà mí.
Neh 6:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli (oṣù kẹsànán), láàrín ọjọ́ méjìléláàdọ́ta. Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa. Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tobiah, èsì láti ọ̀dọ̀ Tobiah sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Juda ti mulẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekaniah ọmọ Arah (Sanballati fẹ́ ọmọ Ṣekaniah), ọmọ rẹ̀ Jehohanani sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Meṣullamu ọmọ Berekiah Síwájú sí í, wọ́n túbọ̀ ń ròyìn iṣẹ́ rere rẹ̀ fún mi, wọ́n sì ń sọ ohun tí mo sọ fún un. Tobiah sì ń kọ àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi láti dẹ́rùbà mí.