Neh 6:1-4
Neh 6:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati Geṣemu, ara Arabia, ati awọn ọta wa iyokù, gbọ́ pe, mo ti mọ odi na, ati pe, kò kù ibi yiya kan ninu rẹ̀, (bi emi kò tilẹ iti gbe ilẹkùn wọnni ro ni ibode li akoko na;) Ni Sanballati ati Geṣemu ranṣẹ si mi, wipe, Wá, jẹ ki a jọ pade ninu ọkan ninu awọn ileto ni pẹtẹlẹ Ono. Ṣugbọn nwọn ngbero ati ṣe mi ni ibi. Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá? Sibẹ nwọn ranṣẹ si mi nigba mẹrin bayi; mo si da wọn lohùn bakanna.
Neh 6:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n sọ fún Sanbalati ati Tobaya ati Geṣemu ará Arabia ati àwọn ọ̀tá wa yòókù pé a ti tún odi náà mọ, ati pé kò sí àlàfo kankan mọ́ (lóòótọ́ n kò tíì ṣe ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè). Sanbalati ati Geṣemu ranṣẹ sí mi, wọ́n ní “Wá, jẹ́ kí á pàdé ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣugbọn wọ́n ti pète láti ṣe mí ní ibi. Mo bá ranṣẹ pada sí wọn pé, mò ń ṣe iṣẹ́ pataki kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní yẹ kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àtiwá rí wọn. Ìgbà mẹrin ni wọ́n ranṣẹ pè mí bẹ́ẹ̀, èsì kan náà sì ni mo fún wọn ní ìgbà mẹrẹẹrin.
Neh 6:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Sanballati, Tobiah Geṣemu ará Arabia àti àwọn ọ̀tá wa tókù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́kù nínú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì ri àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà. Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi; Bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé; “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?” Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan.