Neh 5:4-5
Neh 5:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹlomiran si wipe, Awa ti ṣi owo lati san owo-ori ọba li ori oko wa, ati ọgba-ajara wa. Ati sibẹ ẹran-ara wa si dabi ẹran-ara awọn arakunrin wa, ọmọ wa bi ọmọ wọn: si wo o, awa mu awọn arakunrin wa ati awọn arabinrin wa wá si oko-ẹrú, lati jẹ iranṣẹ, a si ti mu ninu awọn ọmọbinrin wa wá si oko-ẹrú na: awa kò ni agbara lati rà wọn padà: nitori awọn ẹlomiran li o ni oko wa ati ọgbà ajara wa.
Neh 5:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti yá owó láti lè san owó ìṣákọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ oko ati ọgbà àjàrà wa. Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí àwọn arakunrin wa ti rí ni àwa náà rí, àwọn ọmọ wa kò yàtọ̀ sí tiwọn; sibẹsibẹ, à ń fi túlààsì mú àwọn ọmọ wa lọ sóko ẹrú, àwọn ọmọbinrin wa mìíràn sì ti di ẹrú pẹlu bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkan tí a lè ṣe láti dáwọ́ rẹ̀ dúró, nítorí pé ní ìkáwọ́ ẹlòmíràn ni oko wa ati ọgbà àjàrà wa wà.”
Neh 5:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síbẹ̀ àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ní láti yá owó láti san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba lórí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹran-ara kan àti ẹ̀jẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ìlú wa tí àwọn ọmọkùnrin wa sì dára bí í tiwọn, síbẹ̀ àwa ní láti fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa sí oko ẹrú. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọbìnrin wa ti wà lóko ẹrú náà, ṣùgbọ́n àwa kò ní agbára, nítorí àwọn oko àti ọgbà àjàrà wa ti di ti ẹlòmíràn.”