Neh 5:1-19
Neh 5:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN enia ati awọn aya wọn si nkigbe nlanla si awọn ara Juda, arakunrin wọn. Nitori awọn kan wà ti nwọn wipe, Awa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, jẹ pipọ: nitorina awa gba ọkà, awa si jẹ, a si yè. Awọn ẹlomiran wà pẹlu ti nwọn wipe, Awa ti fi oko wa, ọgba-ajara wa, ati ile wa, sọfa, ki awa ki o le rà ọkà ni ìgba ìyan. Ẹlomiran si wipe, Awa ti ṣi owo lati san owo-ori ọba li ori oko wa, ati ọgba-ajara wa. Ati sibẹ ẹran-ara wa si dabi ẹran-ara awọn arakunrin wa, ọmọ wa bi ọmọ wọn: si wo o, awa mu awọn arakunrin wa ati awọn arabinrin wa wá si oko-ẹrú, lati jẹ iranṣẹ, a si ti mu ninu awọn ọmọbinrin wa wá si oko-ẹrú na: awa kò ni agbara lati rà wọn padà: nitori awọn ẹlomiran li o ni oko wa ati ọgbà ajara wa. Emi si binu gidigidi nigbati mo gbọ́ igbe wọn ati ọ̀rọ wọnyi. Mo si ronu ọ̀ran na, mo si ba awọn ijoye ati awọn olori wi, mo si wi fun wọn pe, Ẹnyin ngba ẹdá olukuluku lọwọ arakunrin rẹ̀. Mo si pe apejọ nla tì wọn. Mo si wi fun wọn pe, Awa nipa agbara wa ti rà awọn ara Juda arakunrin wa padà, ti a tà fun awọn keferi; ẹnyin o ha si mu ki a tà awọn arakunrin nyin? tabi ki a ha tà wọn fun wa? Nwọn si dakẹ, nwọn kò ri nkankan dahùn. Mo si wi pẹlu pe, Ohun ti ẹ ṣe kò dara: kò ha yẹ ki ẹ ma rìn ninu ìbẹru Ọlọrun wa, nitori ẹgan awọn keferi ọta wa? Emi pẹlu, ati awọn arakunrin mi, ati awọn ọmọkunrin mi, nyá wọn ni owó ati ọkà, ẹ jẹ ki a pa èlé gbígbà yí tì. Mo bẹ̀ nyin, ẹ fi oko wọn, ọgbà-ajarà wọn, ọgbà-olifi wọn, ati ile wọn, ida-ọgọrun owo na pẹlu, ati ti ọkà, ọti-waini, ati ororo wọn, ti ẹ fi agbara gbà, fun wọn padà loni yi. Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi. Mo si gbọ̀n apo aṣọ mi, mo si wipe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o gbọ̀n olukuluku enia kuro ni ile rẹ̀, ati kuro ninu iṣẹ rẹ̀, ti kò mu ileri yi ṣẹ, ani bayi ni ki a gbọ̀n ọ kuro, ki o si di ofo. Gbogbo ijọ si wipe, Amin! nwọn si fi iyìn fun Oluwa. Awọn enia na si ṣe gẹgẹ bi ileri yi. Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ. Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun. Mo si mba iṣẹ odi yi lọ pẹlu, awa kò si rà oko kan: gbogbo awọn ọmọkunrin mi li o si gbajọ sibẹ si iṣẹ na. Pẹlupẹlu awọn ti o joko ni tabili mi jẹ ãdọjọ enia ninu awọn ara Juda ati ninu awọn ijoye, laika awọn ti o wá sọdọ wa lati ãrin awọn keferi ti o wà yi wa ka. Njẹ ẹran ti a pese fun mi jẹ malũ kan ati ãyo agutan mẹfa; fun ijọ kan ni a pese adiẹ fun mi pẹlu, ati lẹ̃kan ni ijọ mẹwa onirũru ọti-waini: ṣugbọn fun gbogbo eyi emi kò bere onjẹ bãlẹ, nitori iṣẹ na wiwo lori awọn enia yi. Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti mo ti ṣe fun enia yi.
Neh 5:1-19 Yoruba Bible (YCE)
Ọpọlọpọ àwọn eniyan náà, atọkunrin atobinrin, bẹ̀rẹ̀ sí tako àwọn Juu, arakunrin wọn. Àwọn kan ń sọ pé, “Àwa, ati àwọn ọmọ wa, lọkunrin ati lobinrin, a pọ̀, ẹ jẹ́ kí á lọ wá ọkà, kí á lè máa rí nǹkan jẹ, kí á má baà kú.” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti fi ilẹ̀ oko wa yáwó, ati ọgbà àjàrà wa, ati ilé wa, kí á lè rówó ra ọkà nítorí ìyàn tí ó mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti yá owó láti lè san owó ìṣákọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ oko ati ọgbà àjàrà wa. Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí àwọn arakunrin wa ti rí ni àwa náà rí, àwọn ọmọ wa kò yàtọ̀ sí tiwọn; sibẹsibẹ, à ń fi túlààsì mú àwọn ọmọ wa lọ sóko ẹrú, àwọn ọmọbinrin wa mìíràn sì ti di ẹrú pẹlu bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkan tí a lè ṣe láti dáwọ́ rẹ̀ dúró, nítorí pé ní ìkáwọ́ ẹlòmíràn ni oko wa ati ọgbà àjàrà wa wà.” Inú bí mi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn ati ohun tí wọn ń sọ. Mo rò ó lọ́kàn mi, mo sì dá àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè lẹ́bi. Mo sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń ni àwọn arakunrin yín lára.” Mo bá pe ìpàdé ńlá lé wọn lórí, mo sọ fún wọn pé, “Ní tiwa, a ti gbìyànjú níwọ̀n bí agbára wa ti mọ, a ti ra àwọn arakunrin wa tí wọ́n tà lẹ́rú fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pada, ṣugbọn ẹ̀yin tún ń ta àwọn arakunrin yín, kí wọ́n baà lè tún tà wọ́n fún wa!” Wọ́n dákẹ́, wọn kò sì lè fọhùn. Mo wá sọ pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ máa fi ìbẹ̀rù rìn ní ọ̀nà Ọlọrun, kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wa má baà máa kẹ́gàn wa? Pàápàá tí ó jẹ́ pé èmi ati àwọn arakunrin mi ati àwọn iranṣẹ mi ni à ń yá wọn ní owó ati oúnjẹ. Ẹ má gba èlé lọ́wọ́ wọn mọ́, ẹ sì jẹ́ kí á pa gbèsè wọn rẹ́. Ẹ dá ilẹ̀ oko wọn pada fún wọn lónìí, ati ọgbà àjàrà wọn, ati ọgbà igi olifi wọn, ati ilé wọn, ati ìdá kan ninu ọgọrun-un owó èlé tí ẹ gbà, ati ọkà, waini, ati òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn.” Wọ́n sì dáhùn pé, “A óo dá gbogbo rẹ̀ pada, a kò sì ní gba nǹkankan lọ́wọ́ wọn mọ́. A óo ṣe bí o ti wí.” Mo bá pe àwọn alufaa, mo sì mú kí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn yóo ṣe. Mo gbọn àpò ìgbànú mi, mo ní, “Báyìí ni Ọlọrun yóo gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ kúrò ninu ilé rẹ̀ ati kúrò lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Ọlọrun yóo gbọn olúwarẹ̀ dànù lọ́wọ́ òfo.” Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà sì ṣe “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA. Àwọn eniyan náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Siwaju sí i, láti ìgbà tí a ti yàn mí sí ipò gomina ní ilẹ̀ Juda, láti ogun ọdún tí Atasasesi ti jọba sí ọdún kejilelọgbọn, èmi ati arakunrin mi kò jẹ oúnjẹ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bíi gomina. Àwọn gomina yòókù tí wọ́n jẹ ṣiwaju mi a máa ni àwọn eniyan lára, wọn a máa gba oúnjẹ mìíràn ati ọtí waini lọ́wọ́ wọn, yàtọ̀ sí ogoji ìwọ̀n Ṣekeli fadaka tí wọn ń gbà. Àwọn iranṣẹ wọn pàápàá a máa ni àwọn eniyan lára. Ṣugbọn, nítèmi, n kò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo bẹ̀rù Ọlọrun. Gbogbo ara ni mo fi bá wọn ṣiṣẹ́ odi mímọ, sibẹ n kò gba ilẹ̀ kankan, gbogbo àwọn iranṣẹ mi náà sì péjú sibẹ láti ṣiṣẹ́. Siwaju sí i, aadọjọ (150) àwọn Juu ati àwọn ìjòyè ni wọ́n ń jẹun lọ́dọ̀ mi, yàtọ̀ sí àwọn tíí máa wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká. Mààlúù kan ati aguntan mẹfa tí ó dára ni wọ́n ń bá mi pa lojumọ, wọn a tún máa bá mi pa ọpọlọpọ adìẹ. Ní ọjọ́ kẹwaa kẹwaa ni wọ́n máa ń tọ́jú ọpọlọpọ waini sinu awọ fún mi. Sibẹsibẹ, n kò bèèrè owó oúnjẹ tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ gomina, nítorí pé ara tí ń ni àwọn eniyan pupọ jù. Áà! Ọlọrun mi, ranti mi sí rere nítorí gbogbo rere tí mo ti ṣe fún àwọn eniyan wọnyi.
Neh 5:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí àwọn ènìyàn àti àwọn ìyàwó wọn kígbe ńlá sókè sí àwọn Júù arákùnrin wọn. Àwọn kan ń wí pé, “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀; kí àwa kí ó le è jẹ, kí a sì wà láààyè, a gbọdọ̀ rí oúnjẹ.” Àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ti fi oko wa ọgbà àjàrà wa àti ilé wa dógò kí àwa kí ó lè rí oúnjẹ ní àkókò ìyàn.” Síbẹ̀ àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ní láti yá owó láti san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba lórí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹran-ara kan àti ẹ̀jẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ìlú wa tí àwọn ọmọkùnrin wa sì dára bí í tiwọn, síbẹ̀ àwa ní láti fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa sí oko ẹrú. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọbìnrin wa ti wà lóko ẹrú náà, ṣùgbọ́n àwa kò ní agbára, nítorí àwọn oko àti ọgbà àjàrà wa ti di ti ẹlòmíràn.” Èmi bínú gidigidi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn àti àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí. Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀sùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlú u yín! Nítorí náà mo pe àpéjọ ńlá láti bá wọn wí. Mo sì wí fún wọn pé: “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsin yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohunkóhun sọ. Nítorí náà, mo tẹ̀síwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀tá wa? Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró! Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà olifi wọn àti ilé e wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn padà kíákíá.” Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà. Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.” Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí. Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, “Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo!” Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé “Àmín,” wọ́n sì fi ìyìn fún OLúWA. Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí. Síwájú sí í, láti ogún ọdún ọba Artasasta, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Juda, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn baálẹ̀ ìṣáájú—tí ó ti wà ṣáájú mi—gbe àjàgà wúwo lé àwọn ènìyàn lórí yàtọ̀ fún oúnjẹ àti wáìnì wọ́n sì tún gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn. Kódà àwọn ìránṣẹ́ wọn tún jẹ gàba lórí wọn. Ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Dípò bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi jì fún iṣẹ́ lórí odi yìí. Gbogbo àwọn ènìyàn mi péjọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà; a kò sì gba ilẹ̀ kankan. Síwájú sí í, àádọ́jọ (150) àwọn Júù àti àwọn ìjòyè jẹun lórí tábìlì mi, àti pẹ̀lú àwọn tí wọ́n wá bá wa láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni a máa ń pèsè màlúù kan, ààyò àgùntàn mẹ́fà àti adìyẹ fún mi àti lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá ni wọ́n máa ń pèsè onírúurú wáìnì tí ó pọ̀ fún mi. Fún gbogbo èyí, èmi kò béèrè oúnjẹ baálẹ̀, nítorí ohun ti a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pọ̀ jọjọ. Rántí mi, Ọlọ́run mi, fún rere, nítorí fún gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún àwọn ènìyàn yìí.