Neh 4:1-6
Neh 4:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe, nigbati Sanballati gbọ́ pe awa mọ odi na, inu rẹ̀ rú, o si binu pupọ, o si gàn awọn ara Juda. O si sọ niwaju awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ-ogun Samaria pe, Kini awọn alailera Juda wọnyi nṣe yi? nwọn o ha dá wà fun ara wọn bi? nwọn o ha rubọ? nwọn o ha ṣe aṣepari ni ijọkan? nwọn o ha mu okuta ti a ti sun lati inu okìti sọji? Tobiah ara Ammoni si wà li eti ọ̀dọ rẹ̀, o si wipe, Eyi ti nwọn mọ gidi, bi kọ̀lọkọlọ ba gùn u, yio tilẹ wo odi okuta wọn lulẹ̀. Gbọ́, Ọlọrun wa; nitoriti awa di ẹni ẹ̀gan: ki iwọ ki o si dà ẹgan wọn si ori ara wọn, ki o si fi wọn fun ikogun ni ilẹ ìgbekun. Ki o má si bo irekọja wọn, má si jẹ ki a wẹ ẹ̀ṣẹ wọn nù kuro niwaju rẹ: nitoriti nwọn bi ọ ni inu niwaju awọn ọ̀mọle, Bẹ̃ni awa mọ odi na: gbogbo odi na ni a si mọ kàn ara wọn titi de ida meji rẹ̀: nitori awọn enia na ni ọkàn lati ṣiṣẹ.
Neh 4:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Sanbalati gbọ́ pé a ti ń kọ́ odi náà, inú bíi gidigidi, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Juu. Ó sọ lójú àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn Juu aláìlera wọnyi ń ṣé? Ṣé wọn yóo tún ìlú wọn kọ́ ni? Ṣé wọn yóo tún máa rúbọ ni? Ṣé ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n fẹ́ parí rẹ̀ ni? Ṣé wọn yóo lè yọ àwọn òkúta kúrò ninu àlàpà tí wọ́n wà, kí wọn sì fi òkúta tí ó ti jóná gbẹ́ òkúta ìkọ́lé?” Tobaya ará Amoni náà sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun orí ohun tí wọ́n mọ, tí wọn ń pè ní odi olókùúta, wíwó ni yóo wó o lulẹ̀!” Mo bá gbadura pé, “Gbọ́, Ọlọrun wa, nítorí pé wọ́n kẹ́gàn wa. Yí ẹ̀gàn wọn pada lé wọn lórí, kí o sì fi wọ́n lé alágbèédá lọ́wọ́ ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ. Má mójú fo àìdára wọn, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò ninu àkọsílẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ, nítorí pé wọ́n ti mú ọ bínú níwájú àwọn tí wọn ń mọ odi.” Bẹ́ẹ̀ ni, à ń mọ odi náà, a mọ ọ́n já ara wọn yípo, ó sì ga dé ìdajì ibi tí ó yẹ kí ó ga dé, nítorí pé àwọn eniyan náà ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn.
Neh 4:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Sanballati gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀. Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà, ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ-ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí? Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni? Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni? Ṣé wọn yóò parí i rẹ̀ lóòjọ́ ni bí? Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti sun láti inú òkìtì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà?” Tobiah ará Ammoni, ẹni tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wí pé, “Ohun tí wọ́n ń mọ—bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá gùn ún sókè, yóò fọ́ odi òkúta wọn lulẹ̀!” Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn. Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn. Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé. Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajì gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an wọn.