Neh 4:1-23

Neh 4:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

O SI ṣe, nigbati Sanballati gbọ́ pe awa mọ odi na, inu rẹ̀ rú, o si binu pupọ, o si gàn awọn ara Juda. O si sọ niwaju awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ-ogun Samaria pe, Kini awọn alailera Juda wọnyi nṣe yi? nwọn o ha dá wà fun ara wọn bi? nwọn o ha rubọ? nwọn o ha ṣe aṣepari ni ijọkan? nwọn o ha mu okuta ti a ti sun lati inu okìti sọji? Tobiah ara Ammoni si wà li eti ọ̀dọ rẹ̀, o si wipe, Eyi ti nwọn mọ gidi, bi kọ̀lọkọlọ ba gùn u, yio tilẹ wo odi okuta wọn lulẹ̀. Gbọ́, Ọlọrun wa; nitoriti awa di ẹni ẹ̀gan: ki iwọ ki o si dà ẹgan wọn si ori ara wọn, ki o si fi wọn fun ikogun ni ilẹ ìgbekun. Ki o má si bo irekọja wọn, má si jẹ ki a wẹ ẹ̀ṣẹ wọn nù kuro niwaju rẹ: nitoriti nwọn bi ọ ni inu niwaju awọn ọ̀mọle, Bẹ̃ni awa mọ odi na: gbogbo odi na ni a si mọ kàn ara wọn titi de ida meji rẹ̀: nitori awọn enia na ni ọkàn lati ṣiṣẹ. O si ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati awọn ara Arabia, ati awọn ara Ammoni, ati awọn ara Aṣdodi gbọ́ pe, a mọ odi Jerusalemu de oke, ati pe a bẹ̀rẹ si tun ibi ti o ya ṣe, inu wọn ru gidigidi. Gbogbo wọn si jọ gbìmọ pọ̀ lati wá iba Jerusalemu jà, ati lati ṣe ika si i. Ṣugbọn awa gba adura wa si Ọlọrun wa, a si yan iṣọ si wọn lọsan ati loru, nitori wọn. Juda si wipe, Agbara awọn ti nru ẹrù dínkù, àlapa pupọ li o wà, tobẹ̃ ti awa kò fi le mọ odi na. Awọn ọta wa si wipe, Nwọn kì yio mọ̀, bẹ̃ni nwọn kì yio ri titi awa o fi de ãrin wọn, ti a o fi pa wọn, ti a o si da iṣẹ na duro. O si ṣe, nigbati awọn ara Juda ti o wà li agbegbe wọn de, nwọn wi fun wa nigba mẹwa pe, Lati ibi gbogbo wá li ẹnyin o pada tọ̀ wa wá. Nitorina ni mo yàn awọn enia si ibi ti o rẹlẹ lẹhin odi, ati si ibi gbangba, mo tilẹ yàn awọn enia gẹgẹ bi idile wọn, pẹlu idà wọn, ọ̀kọ wọn, ati ọrun wọn. Mo si wò, mo si dide, mo si wi fun awọn ìjoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Ẹ máṣe jẹ ki ẹ̀ru wọn bà nyin, ẹ ranti Oluwa ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ki ẹ si jà fun awọn arakunrin nyin, awọn ọmọkunrin nyin, ati awọn ọmọbinrin nyin, awọn aya nyin, ati ile nyin. O si ṣe, nigbati awọn ọta wa gbọ́ pe, o di mimọ̀ fun wa, Ọlọrun ti sọ ìmọ wọn di asan, gbogbo wa si padà si odi na, olukuluku si iṣẹ rẹ̀. O si ṣe, lati ọjọ na wá, idaji awọn ọmọkunrin mi ṣe iṣẹ na, idaji keji di ọ̀kọ, apata, ati ọrun, ati ihamọra mu; awọn olori si duro lẹhin gbogbo ile Juda. Awọn ti nmọ odi, ati awọn ti nrù ẹrù ati awọn ti o si ndi ẹrù, olukuluku wọn nfi ọwọ rẹ̀ kan ṣe iṣẹ, nwọn si fi ọwọ keji di ohun ìja mu. Olukuluku awọn ọmọ kọ́ idà rẹ̀ li ẹgbẹ rẹ̀, bẹni nwọn si mọ odi. Ẹniti nfọn ipè wà li eti ọdọ mi. Mo si sọ fun awọn ijoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Iṣẹ́ na tobi o si pọ̀, a si ya ara wa lori odi, ẹnikini jina si ẹnikeji. Ni ibi ti ẹnyin ba gbọ́ iro ipè, ki ẹ wá sọdọ wa: Ọlọrun wa yio jà fun wa. Bẹ̃ni awa ṣe iṣẹ na: idaji wọn di ọ̀kọ mu lati kùtukutu owurọ titi irawọ fi yọ. Li àkoko kanna pẹlu ni mo sọ fun awọn enia pe, Jẹ ki olukuluku pẹlu ọmọkunrin rẹ̀ ki o sùn ni Jerusalemu, ki nwọn le jẹ ẹṣọ fun wa li oru, ki nwọn si le ṣe iṣẹ li ọsan. Bẹ̃ni kì iṣe emi, tabi awọn arakunrin mi, tabi awọn ọmọkunrin mi, tabi awọn oluṣọ ti ntọ̀ mi lẹhin, kò si ẹnikan ninu wa ti o bọ́ aṣọ kuro, olukuluku mu ohun ìja rẹ̀ li ọwọ fun ogun.

Neh 4:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Sanbalati gbọ́ pé a ti ń kọ́ odi náà, inú bíi gidigidi, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Juu. Ó sọ lójú àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn Juu aláìlera wọnyi ń ṣé? Ṣé wọn yóo tún ìlú wọn kọ́ ni? Ṣé wọn yóo tún máa rúbọ ni? Ṣé ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n fẹ́ parí rẹ̀ ni? Ṣé wọn yóo lè yọ àwọn òkúta kúrò ninu àlàpà tí wọ́n wà, kí wọn sì fi òkúta tí ó ti jóná gbẹ́ òkúta ìkọ́lé?” Tobaya ará Amoni náà sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun orí ohun tí wọ́n mọ, tí wọn ń pè ní odi olókùúta, wíwó ni yóo wó o lulẹ̀!” Mo bá gbadura pé, “Gbọ́, Ọlọrun wa, nítorí pé wọ́n kẹ́gàn wa. Yí ẹ̀gàn wọn pada lé wọn lórí, kí o sì fi wọ́n lé alágbèédá lọ́wọ́ ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ. Má mójú fo àìdára wọn, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò ninu àkọsílẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ, nítorí pé wọ́n ti mú ọ bínú níwájú àwọn tí wọn ń mọ odi.” Bẹ́ẹ̀ ni, à ń mọ odi náà, a mọ ọ́n já ara wọn yípo, ó sì ga dé ìdajì ibi tí ó yẹ kí ó ga dé, nítorí pé àwọn eniyan náà ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ati Tobaya ati àwọn ará Arabu, ati àwọn ará Amoni, ati àwọn ará Aṣidodu, gbọ́ pé a ti ń ṣe àtúnṣe àwọn odi Jerusalẹmu ati pé a ti ń dí àwọn ihò ibẹ̀, inú bí wọn gidigidi. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ láti wá gbógun ti Jerusalẹmu kí wọ́n lè dá rúkèrúdò sílẹ̀. Ṣugbọn a gbadura sí Ọlọrun wa, a sì yan àwọn olùṣọ́ láti máa ṣọ́ ibẹ̀ tọ̀sán-tòru. Àwọn ará Juda bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé, “Agbára àwa tí à ń ṣe iṣẹ́ ń dín kù, iṣẹ́ sì tún pọ̀ nílẹ̀; ǹjẹ́ a ó lè mọ odi náà mọ́ báyìí?” Àwọn ọ̀tá wa sì wí pé, “Wọn kò ní mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní rí wa títí tí a óo fi dé ọ̀dọ̀ wọn, tí a óo pa wọ́n, tí iṣẹ́ náà yóo sì dúró.” Ṣugbọn àwọn Juu tí wọn ń gbé ààrin wọn wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ọpọlọpọ ìgbà, wọ́n sì sọ fún wa pé, “Láti gbogbo ilẹ̀ wọn ni wọn yóo ti dìde ogun sí wa.” Nítorí náà mo fi àwọn eniyan ṣọ́ gbogbo ibi tí odi ìlú bá ti gba ibi tí ilẹ̀ ti dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, mo yan olukuluku ní ìdílé ìdílé, wọ́n ń ṣọ́ odi ní agbègbè wọn pẹlu idà, ọ̀kọ̀, ati ọrun wọn. Mo dìde, mo wò yíká, mo bá sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan yòókù pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. Ẹ ranti OLUWA tí ó tóbi tí ó sì bani lẹ́rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arakunrin yín, ati àwọn ọmọkunrin yín, àwọn ọmọbinrin yín, ati àwọn iyawo yín, ati àwọn ilé yín.” Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa ti gbọ́ pé a ti mọ àṣírí ète wọn, ati pé Ọlọrun ti da ìmọ̀ wọn rú, gbogbo wa pada sí ibi odi náà, olukuluku sì ń ṣe iṣẹ́ tirẹ̀. Láti ọjọ́ náà, ìdajì àwọn òṣìṣẹ́ mi ní ń bá iṣẹ́ odi mímọ lọ, ìdajì yòókù sì dira pẹlu ọ̀kọ̀, àṣíborí, ọrun ati aṣọ ogun. Àwọn ìjòyè sì wà lẹ́yìn gbogbo àwọn eniyan Juda, tí ń mọ odi lọ́wọ́. Àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ń fi ọwọ́ kan ṣiṣẹ́, wọ́n sì mú ohun ìjà ní ọwọ́ keji. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ náà fi idà kọ́ èjìká bí ó ṣe ń mọ odi lọ. Ẹni tí ó ń fọn fèrè sì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ mi. Mo sì sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè ati àwọn eniyan yòókù pé, “Iṣẹ́ náà pọ̀ gan-an, odi yìí sì gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ó mú kí á jìnnà sí ara wa. Ibikíbi tí ẹ bá wà, tí ẹ bá ti gbọ́ fèrè, ẹ wá péjọ sọ́dọ̀ wa. Ọlọrun wa yóo jà fún wa.” Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà tí àwọn apá kan sì gbé idà lọ́wọ́ láti àárọ̀ di alẹ́. Mo tún sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Kí olukuluku ati iranṣẹ rẹ̀ sùn ní Jerusalẹmu, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ìlú lálẹ́, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní ojú ọ̀sán.” Nítorí náà, àtèmi ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn iranṣẹ mi, ati àwọn olùṣọ́ tí wọ́n tẹ̀lé mi, a kò bọ́ aṣọ lọ́rùn tọ̀sán-tòru, gbogbo wa ni a di ihamọra wa, tí a sì mú nǹkan ìjà lọ́wọ́.

Neh 4:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Sanballati gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀. Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà, ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ-ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí? Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni? Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni? Ṣé wọn yóò parí i rẹ̀ lóòjọ́ ni bí? Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti sun láti inú òkìtì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà?” Tobiah ará Ammoni, ẹni tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wí pé, “Ohun tí wọ́n ń mọ—bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá gùn ún sókè, yóò fọ́ odi òkúta wọn lulẹ̀!” Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn. Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn. Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé. Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajì gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati, Tobiah, àwọn ará Arabia, ará Ammoni, àti àwọn ènìyàn Aṣdodu gbọ́ pé àtúnṣe odi Jerusalẹmu ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi. Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jerusalẹmu jà àti láti dìde wàhálà sí í. Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí. Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Juda wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.” Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀tá wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárín wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.” Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, “Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọlù wá.” Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí mo wo àwọn nǹkan yíká, mo dìde mo sì wí fún àwọn ọlọ́lá àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tókù pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù u wọn. Ẹ rántí OLúWA, ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ilé yín.” Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ pé àwa ti mọ èrò wọn àti wí pé Ọlọ́run ti bà á jẹ́, gbogbo wa padà sí ibi odi, ẹnìkọ̀ọ̀kan sí ibi iṣẹ́ tirẹ̀. Láti ọjọ́ náà lọ, ìdajì àwọn ènìyàn ń ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn ìdajì tókù múra pẹ̀lú ọ̀kọ̀, asà, ọrun àti ìhámọ́ra. Àwọn ìjòyè sì pín ara wọn sẹ́yìn gbogbo ènìyàn Juda. Àwọn ẹni tí ó ń mọ odi. Àwọn tí ń ru àwọn ohun èlò ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú ọwọ́ kan, wọ́n sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà mú, olúkúlùkù àwọn ọ̀mọ̀lé fi idà wọn sí ẹ̀gbẹ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ń fọn ìpè dúró pẹ̀lú mi. Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tókù pé, “Iṣẹ́ náà fẹ̀ ó sì pọ̀, a sì ti jìnnà sí ara wa púpọ̀ lórí odi. Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!” Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ. Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jerusalẹmu ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.” Bẹ́ẹ̀ ni èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà pẹ̀lú mi kò bọ́ aṣọ wa, olúkúlùkù wa ní ohun ìjà tirẹ̀, kódà nígbà tí wọ́n bá ń lọ pọn omi.