Neh 2:7-8
Neh 2:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pẹlupẹlu mo wi fun ọba pe, bi o ba wù ọba, ki o fun mi ni iwe si awọn bãlẹ li oke odò, ki nwọn le mu mi kọja titi emi o fi de Juda; Ati iwe kan fun Asafu, oluṣọ igbo ọba, ki o le fun mi ni igi fun atẹrigba ẹnu-ọ̀na odi lẹba ile Ọlọrun ati fun odi ilu, ati fun ile ti emi o wọ̀. Ọba si fun mi gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun mi lara mi.
Neh 2:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Mo fún ọba lésì pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn bẹ́ẹ̀, kí kabiyesi kọ̀wé lé mi lọ́wọ́ kí n lọ fún àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò, kí wọ́n lè jẹ́ kí n rékọjá lọ sí Juda, kí ó kọ ìwé sí Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, kí ó fún mi ní igi kí n fi ṣe odi ẹnu ọ̀nà tẹmpili, ati ti odi ìlú, ati èyí tí n óo fi kọ́ ilé tí n óo máa gbé.” Ọba ṣe gbogbo ohun tí mo bèèrè fún mi, nítorí pé Ọlọrun lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi.
Neh 2:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì tún wí fún ọba pé, “Bí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálẹ̀ òkè odò Eufurate kí wọ́n le mú mi kọjá títí èmi yóò fi dé Juda láìléwu Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹmpili àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé?” Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lórí mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi.