Neh 2:6-9
Neh 2:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọba si wi fun mi pe, (ayaba si joko tì i) ajo rẹ yio ti pẹ to? nigbawo ni iwọ o si pada? Bẹli o wù ọba lati rán mi; mo si dá àkoko kan fun u. Pẹlupẹlu mo wi fun ọba pe, bi o ba wù ọba, ki o fun mi ni iwe si awọn bãlẹ li oke odò, ki nwọn le mu mi kọja titi emi o fi de Juda; Ati iwe kan fun Asafu, oluṣọ igbo ọba, ki o le fun mi ni igi fun atẹrigba ẹnu-ọ̀na odi lẹba ile Ọlọrun ati fun odi ilu, ati fun ile ti emi o wọ̀. Ọba si fun mi gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun mi lara mi. Nigbana ni mo de ọdọ awọn bãlẹ li oke odo mo si fi iwe ọba fun wọn: Ọba si ti rán awọn olori-ogun ati ẹlẹṣin pẹlu mi.
Neh 2:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Ayaba wà ní ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “O óo lò tó ọjọ́ mélòó lọ́hùn-ún? Ìgbà wo ni o sì fẹ́ pada?” Inú ọba dùn láti rán mi lọ, èmi náà sì dá ìgbà fún un. Mo fún ọba lésì pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn bẹ́ẹ̀, kí kabiyesi kọ̀wé lé mi lọ́wọ́ kí n lọ fún àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò, kí wọ́n lè jẹ́ kí n rékọjá lọ sí Juda, kí ó kọ ìwé sí Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, kí ó fún mi ní igi kí n fi ṣe odi ẹnu ọ̀nà tẹmpili, ati ti odi ìlú, ati èyí tí n óo fi kọ́ ilé tí n óo máa gbé.” Ọba ṣe gbogbo ohun tí mo bèèrè fún mi, nítorí pé Ọlọrun lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi. Mo bá tọ àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò lọ mo fún wọn ní lẹta tí ọba kọ. Ọba rán àwọn olórí ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tẹ̀lé mi.
Neh 2:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan. Mo sì tún wí fún ọba pé, “Bí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálẹ̀ òkè odò Eufurate kí wọ́n le mú mi kọjá títí èmi yóò fi dé Juda láìléwu Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹmpili àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé?” Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lórí mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi. Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lú mi.