Neh 2:19-20
Neh 2:19-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati Sanballati ara Horoni, ati Tobiah iranṣẹ, ara Ammoni, ati Gesẹmu, ara Arabia, gbọ́, nwọn fi wa rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wa, nwọn si wipe, Kini ẹnyin nṣe yi? ẹnyin o ha ṣọ̀tẹ si ọba bi? Nigbana ni mo da wọn li ohùn mo si wi fun wọn pe, Ọlọrun ọrun, On o ṣe rere fun wa; nitorina awa iranṣẹ rẹ̀ yio dide lati mọ odi: ṣugbọn ẹnyin kò ni ipin tabi ipa tabi ohun iranti ni Jerusalemu.
Neh 2:19-20 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni ati Geṣemu ará Arabia gbọ́, wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń pẹ̀gàn wa pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ̀ ń dìtẹ̀ mọ́ ọba ni?” Mo fún wọn lésì pé, “Ọlọrun ọ̀run yóo mú wa ṣe àṣeyọrí, àwa iranṣẹ rẹ̀ yóo múra, a óo sì mọ odi náà, ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò ní ìpín, tabi ẹ̀tọ́, tabi ìrántí ní Jerusalẹmu.”
Neh 2:19-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati ará a Horoni, Tobiah ara olóyè Ammoni àti Geṣemu ará a Arabia gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé, “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?” Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jerusalẹmu.”