Neh 2:17-20
Neh 2:17-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Ẹnyin ri ibanujẹ ti awa wà, bi Jerusalemu ti di ahoro, ẹnu-ọ̀na rẹ̀ li a si fi iná sun: ẹ wá, ẹ jẹ ki a mọ odi Jerusalemu, ki a má ba jẹ ẹni-ẹgàn mọ! Nigbana ni mo si sọ fun wọn niti ọwọ Ọlọrun mi, ti o dara li ara mi; ati ọ̀rọ ọba ti o ba mi sọ. Nwọn si wipe, Jẹ ki a dide, ki a si mọ odi! Bẹni nwọn gba ara wọn ni iyanju fun iṣẹ rere yi. Ṣugbọn nigbati Sanballati ara Horoni, ati Tobiah iranṣẹ, ara Ammoni, ati Gesẹmu, ara Arabia, gbọ́, nwọn fi wa rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wa, nwọn si wipe, Kini ẹnyin nṣe yi? ẹnyin o ha ṣọ̀tẹ si ọba bi? Nigbana ni mo da wọn li ohùn mo si wi fun wọn pe, Ọlọrun ọrun, On o ṣe rere fun wa; nitorina awa iranṣẹ rẹ̀ yio dide lati mọ odi: ṣugbọn ẹnyin kò ni ipin tabi ipa tabi ohun iranti ni Jerusalemu.
Neh 2:17-20 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí irú ìyọnu tí ó dé bá wa! Ẹ wò ó bí Jerusalẹmu ṣe parun tí àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì jóná. Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á kọ́ odi Jerusalẹmu, kí á lè fi òpin sí ìtìjú tí ó dé bá wa.” Mo sọ fún wọn nípa bí Ọlọrun ṣe lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi ati nípa ọ̀rọ̀ tí ọba bá mi sọ. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á múra kí á sì kọ́ ọ.” Wọ́n sì gbáradì láti ṣe iṣẹ́ rere náà. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni ati Geṣemu ará Arabia gbọ́, wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń pẹ̀gàn wa pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ̀ ń dìtẹ̀ mọ́ ọba ni?” Mo fún wọn lésì pé, “Ọlọrun ọ̀run yóo mú wa ṣe àṣeyọrí, àwa iranṣẹ rẹ̀ yóo múra, a óo sì mọ odi náà, ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò ní ìpín, tabi ẹ̀tọ́, tabi ìrántí ní Jerusalẹmu.”
Neh 2:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”. Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi. Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí. Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati ará a Horoni, Tobiah ara olóyè Ammoni àti Geṣemu ará a Arabia gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé, “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?” Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jerusalẹmu.”