Neh 2:17-18
Neh 2:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Ẹnyin ri ibanujẹ ti awa wà, bi Jerusalemu ti di ahoro, ẹnu-ọ̀na rẹ̀ li a si fi iná sun: ẹ wá, ẹ jẹ ki a mọ odi Jerusalemu, ki a má ba jẹ ẹni-ẹgàn mọ! Nigbana ni mo si sọ fun wọn niti ọwọ Ọlọrun mi, ti o dara li ara mi; ati ọ̀rọ ọba ti o ba mi sọ. Nwọn si wipe, Jẹ ki a dide, ki a si mọ odi! Bẹni nwọn gba ara wọn ni iyanju fun iṣẹ rere yi.
Neh 2:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí irú ìyọnu tí ó dé bá wa! Ẹ wò ó bí Jerusalẹmu ṣe parun tí àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì jóná. Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á kọ́ odi Jerusalẹmu, kí á lè fi òpin sí ìtìjú tí ó dé bá wa.” Mo sọ fún wọn nípa bí Ọlọrun ṣe lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi ati nípa ọ̀rọ̀ tí ọba bá mi sọ. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á múra kí á sì kọ́ ọ.” Wọ́n sì gbáradì láti ṣe iṣẹ́ rere náà.
Neh 2:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”. Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi. Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí.