Neh 2:11-13
Neh 2:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹni mo de Jerusalemu, mo si wà nibẹ̀ ni ọjọ mẹta. Mo si dide li oru, emi ati ọkunrin diẹ pẹlu mi: emi kò si sọ fun enia kan ohun ti Ọlọrun mi fi si mi li ọkàn lati ṣe ni Jerusalemu: bẹni kò si ẹranko kan pẹlu mi, bikoṣe ẹranko ti mo gùn. Mo si jade li oru ni ibode afonifoji, ani niwaju kanga Dragoni, ati li ẹnu-ọ̀na ãtàn; mo si wò odi Jerusalemu ti a wó lulẹ̀, ati ẹnu-ọ̀na ti a fi iná sun.
Neh 2:11-13 Yoruba Bible (YCE)
Mo bá wá sí Jerusalẹmu mo sì wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn. Mo gbéra lóru, mo gba Ẹnubodè Àfonífojì. Mo jáde sí kànga Diragoni, mo gba ibẹ̀ lọ sí Ẹnubodè Ààtàn. Bí mo ti ń lọ, mò ń wo àwọn ògiri Jerusalẹmu tí wọ́n ti wó lulẹ̀ ati àwọn ẹnu ọ̀nà tí wọ́n ti jó níná.
Neh 2:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì lọ sí Jerusalẹmu, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn. Ní òru, mo jáde lọ sí Àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu Ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.