Neh 1:1-2
Neh 1:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Nehemiah ọmọ Hakaliah. O si ṣe ninu oṣu Kisleu, ni ogún ọdun, nigba tí mo wà ni Ṣuṣani ãfin. Ni Hanani, ọkan ninu awọn arakunrin mi, on ati awọn ọkunrin kan lati Juda wá sọdọ mi; mo si bi wọn lere niti awọn ara Juda ti o salà, ti o kù ninu awọn igbekùn, ati niti Jerusalemu.
Neh 1:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ìtàn Nehemaya ọmọ Hakalaya. Ní oṣù Kisilefi, ní ogún ọdún tí Atasasesi jọba ní ilẹ̀ Pasia, mo wà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ náà, Hanani, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi, pẹlu àwọn kan tọ̀ mí wá láti ilẹ̀ Juda, mo bá bèèrè àwọn Juu tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lọ sóko ẹrú, mo sì tún bèèrè nípa Jerusalẹmu.
Neh 1:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ Nehemiah ọmọ Hakaliah: Ní oṣù Kisleu ní ogún ọdún (ìjọba Ahaswerusi ọba Persia) nígbà tí mo wà ní ààfin Susa, Hanani, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Juda pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jerusalẹmu.