Nah 1:1-15

Nah 1:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ-ÌMỌ̀ niti Ninefe. Iwe iran Nahumu ara Elkoṣi. Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀. Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀. O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ. Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀. Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata. Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e. Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀. Kili ẹnyin ngbirò si Oluwa? on o ṣe iparun de opin, ipọnju kì yio dide lẹrinkeji. Nitori sã ti a ba ká wọn jọ bi ẹ̀gun, ati sã ti wọn iba mu amupara bi ọmùti, a o run wọn gẹgẹ bi koriko ti o ti gbẹ de opin. Ẹnikan ti ọdọ rẹ jade wá, ti o ngbirò ibi si Oluwa, olugbìmọ buburu. Bayi ni Oluwa wi; bi nwọn tilẹ pé, ti nwọn si pọ̀ niye, ṣugbọn bayi ni a o ke nwọn lulẹ, nigbati on o ba kọja. Bi mo tilẹ ti pọn ọ loju, emi kì yio pọn ọ loju mọ. Nitori nisisiyi li emi o fà ajàga rẹ̀ kuro li ọrun rẹ, emi o si dá idè rẹ wọnni li agbede-meji. Oluwa si ti fi aṣẹ kan lelẹ nitori rẹ pe, ki a má ṣe gbìn ninu orukọ rẹ mọ: lati inu ile ọlọrun rẹ wá li emi o ke ere fifin ati ere didà kuro: emi o wà ibojì rẹ; nitori ẹgbin ni iwọ. Wò o lori oke nla ẹsẹ̀ ẹniti o mu ihìn rere wá, ẹniti o nkede alafia! Iwọ Juda, pa aṣẹ rẹ ti o ni irònu mọ, san ẹ̀jẹ́ rẹ: nitori enia buburu kì yio kọja lãrin rẹ mọ; a ti ké e kuro patapata.

Nah 1:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí; tí a kọ sinu ìwé ìran tí Nahumu ará Elikoṣi rí nípa ìlú Ninefe. OLUWA tíí jowú tíí sìí máa gbẹ̀san ni Ọlọrun. OLUWA a máa gbẹ̀san, a sì máa bínú. OLUWA a máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, a sì máa fi ìrúnú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLUWA kì í tètè bínú; ó lágbára lọpọlọpọ, kì í sìí dá ẹni tí ó bá jẹ̀bi láre. Ipa ọ̀nà rẹ̀ wà ninu ìjì ati ẹ̀fúùfù líle, awọsanma sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ, ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu; koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ, òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀. Àwọn òkè ńláńlá mì tìtì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì yọ́. Ilẹ̀ di asán níwájú rẹ̀, ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di òfo. Bí ó bá ń bínú ta ló lè dúró? Ta ló lè farada ibinu gbígbóná rẹ̀? Ìrúnú rẹ̀ a máa ru jáde bí ahọ́n iná, a sì máa fọ́ àwọn àpáta níwájú rẹ̀. OLUWA ṣeun, òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú; ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò. Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀ ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀; yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn. Èrò ibi wo ni ẹ̀ ń gbà sí OLUWA? Yóo wulẹ̀ pa yín run patapata ni; kò sì sí ẹni tí OLUWA yóo gbẹ̀san lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tí yóo lè ṣẹ̀ ẹ́ lẹẹkeji. Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí, àní bíi koríko gbígbẹ. Ṣebí ọ̀kan ninu yín ni ó ń gbìmọ̀ burúkú sí OLUWA, tí ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú? OLUWA wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Siria lágbára, tí wọ́n sì pọ̀, a óo pa wọ́n run, wọn yóo sì parẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti jẹ ẹ̀yin ọmọ Juda níyà tẹ́lẹ̀, n kò ní jẹ yín níyà mọ́. N óo bọ́ àjàgà Asiria kúrò lọ́rùn yín, n óo sì já ìdè yín.” OLUWA ti pàṣẹ nípa Asiria, pé: “A kò ní ranti orúkọ rẹ mọ́, ìwọ ilẹ̀ Asiria, n óo run àwọn ère tí ẹ̀yin ará Asiria gbẹ́, ati àwọn tí ẹ dà, tí wọ́n wà ní ilé oriṣa rẹ, n óo gbẹ́ ibojì rẹ, nítorí ẹlẹ́gbin ni ọ́.” Wo ẹsẹ̀ ẹni tí ó ń mú ìyìn rere wá lórí àwọn òkè ńláńlá, ẹni tí ń kéde alaafia! Ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin ará Juda, kí ẹ sì san àwọn ẹ̀jẹ́ yín, nítorí ẹni ibi kò ní gbógun tì yín mọ́, a ti pa á run patapata.

Nah 1:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi. OLúWA Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san. OLúWA ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú OLúWA ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ OLúWA lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; OLúWA kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, Ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ, Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀. Rere ni OLúWA, òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀. Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí OLúWA? Òun yóò fi òpin sí i, ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbèrò ibi sí OLúWA ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú. Báyìí ni OLúWA wí: “Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye, Ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀, nígbà tí òun ó bá kọjá. Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójú mọ́. Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ èmi yóò já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.” OLúWA ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Ninefe: “Ìwọ kì yóò ni irú-ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́, Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run tí ó wà nínú tẹmpili àwọn ọlọ́run rẹ. Èmi yóò wa ibojì rẹ, nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.” Wò ó, lórí àwọn òkè, àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá, ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà, Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́, kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́; wọn yóò sì parun pátápátá.