Mak 9:33-50
Mak 9:33-50 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wá si Kapernaumu: nigbati o si wà ninu ile o bi wọn lẽre, wipe, Kili ohun ti ẹnyin mba ara nyin jiyan si li ọ̀na? Ṣugbọn nwọn dakẹ: nitori nwọn ti mba ara wọn jiyan pe, tali ẹniti o pọ̀ju. O si joko, o si pè awọn mejila na, o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba nfẹ ṣe ẹni iwaju, on na ni yio ṣe ẹni ikẹhin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn. O si mu ọmọ kekere kan, o fi i sarin wọn; nigbati o si gbé e si apa rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba gbà ọkan ninu iru awọn ọmọ kekere wọnyi li orukọ mi, o gbà mi: ẹnikẹni ti o ba si gbà mi, ki iṣe emi li o gbà, ṣugbọn o gbà ẹniti o rán mi. Johanu si da a lohùn, o wipe, Olukọni, awa ri ẹnikan nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade, on kò si tọ̀ wa lẹhin: awa si da a lẹkun, nitoriti ko tọ̀ wa lẹhin: Jesu si wipe, Ẹ máṣe da a lẹkun mọ́: nitori kò si ẹnikan ti yio ṣe iṣẹ agbara li orukọ mi, ti o si le yara sọ ibi si mi. Nitori ẹniti ko ba kọ oju ija si wa, o wà ni iha tiwa. Nitori ẹnikẹni ti o ba fi ago omi fun nyin mu li orukọ mi, nitoriti ẹnyin jẹ ti Kristi, lõtọ ni mo wi fun nyin, on kì yio padanù ère rẹ̀ bi o ti wù ki o ri. Ẹnikẹni ti o ba si mu ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o sàn fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si sọ ọ sinu omi okun. Bi ọwọ́ rẹ, ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ lọ si ibi iye, jù ki o li ọwọ mejeji ki o lọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku, Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na kì si ikú. Bi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsè, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akesẹ lọ si ibi ìye, jù ki o li ẹsẹ mejeji ki a gbé ọ sọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku, Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú. Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade: o sàn fun ọ ki o lọ si ijọba Ọlọrun li olojukan, jù ki o li oju mejeji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apadi, Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú. Nitoripe olukukuku li a o fi iná dùn, ati gbogbo ẹbọ li a o si fi iyọ̀ dùn. Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba sọ agbara rẹ̀ nù, kili ẹ o fi mu u dùn? Ẹ ni iyọ̀ ninu ara nyin, ki ẹ si ma wà li alafia lãrin ara nyin.
Mak 9:33-50 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, tí wọ́n wọ inú ilé, ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ lọ́nà?” Wọ́n bá dákẹ́ nítorí ní ọ̀nà, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn lórí ta ni ó ṣe pataki jùlọ. Lẹ́yìn tí ó ti jókòó, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ọ̀gá, ó níláti ṣe iranṣẹ fún gbogbo eniyan.” Ó bá fa ọmọde kan dìde ní ààrin wọn, ó gbé e sí ọwọ́ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan ninu àwọn ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, kì í ṣe èmi ni ó gbà, ṣugbọn ó gba ẹni tí ó rán mi wá sí ayé.” Johanu wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a rí ẹnìkan tí ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ṣugbọn a gbìyànjú láti dá a lẹ́kun, nítorí kì í ṣe ara wa.” Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Ẹ má ṣe dá a lẹ́kun, nítorí kò sí ẹni tí yóo fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóo yára sọ ọ̀rọ̀ ibi nípa mi. Nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí wa, tiwa ni. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fun yín ní omi mu nítorí tèmi, nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo rí èrè rẹ̀ gbà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun. Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àléébù ara, jù pé kí o ní ọwọ́ mejeeji kí o wọ iná àjóòkú, [ níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.] Bí ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ kan kí o sì wọ inú ìyè jù pé kí o ní ẹsẹ̀ mejeeji kí á sì sọ ọ́ sinu iná, [ níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.] Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ ìjọba Ọlọrun pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú mejeeji kí a sì sọ ọ́ sinu iná, níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú. “Iyọ̀ níí sọ ẹbọ di mímọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó jẹ́ pé iná ni a óo fi sọ gbogbo eniyan di mímọ́. “Iyọ̀ dára, ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni yóo ṣe tún lè dùn mọ́? “Ẹ ní iyọ̀ ninu ara yín, nígbà náà ni alaafia yóo wà láàrin yín.”
Mak 9:33-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n dé sí Kapernaumu. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tán nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé, ta ni ẹni tí ó pọ̀jù? Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.” Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gbà ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.” Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Johanu sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwa rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú wa.” Jesu sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi. Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa. Lóòótọ́ ni mo sọ fún ún yín bí ẹnikẹ́ni bá fún un yín ní ife omi kan nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, dájúdájú ẹni náà kì yóò sọ èrè rẹ̀ nù bí ó ti wù kí ó rí. “Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú Òkun. Bí ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o ṣe akéwọ́ lọ sí ibi ìyè, ju o ní ọwọ́ méjèèjì kí o lọ sí ọ̀run àpáàdì, sínú iná àjóòkú. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nà án kì í kú. Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnù, ó sàn kí ó di akesẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹsẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nà án kì í sì í ku. Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì. Níbi ti “ ‘kòkòrò wọn kì í kú, tí iná kì í sì í kú.’ Níbẹ̀ ni a ó ti fi iná dán ẹnìkọ̀ọ̀kan wò. “Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mú un dùn? Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.”