Mak 9:2-7
Mak 9:2-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lẹhin ijọ mẹfa Jesu si mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, o si mu wọn lọ sori òke giga li apakan awọn nikan: ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn. Aṣọ rẹ̀ si di didán, o si funfun gidigidi; afọṣọ kan li aiye kò le fọ̀ aṣọ fún bi iru rẹ̀. Elijah pẹlu Mose si farahàn fun wọn: nwọn si mba Jesu sọ̀rọ. Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah. On kò sá mọ̀ eyi ti iba wi; nitori ẹ̀ru bà wọn gidigidi. Ikuku kan si wá, o ṣiji bò wọn; ohùn kan si ti inu ikuku na wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.
Mak 9:2-7 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọ sí orí òkè gíga kan, àwọn mẹta yìí nìkan ni ó mú lọ. Ìrísí rẹ̀ bá yipada lójú wọn. Ẹ̀wù rẹ̀ ń dán, ó funfun láúláú, kò sí alágbàfọ̀ kan ní ayé tí ó lè fọ aṣọ kí ó funfun tóbẹ́ẹ̀. Wọ́n rí Elija pẹlu Mose tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀. Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, ó dára tí a wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pàgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.” Ẹ̀rù tí ó bà wọ́n pupọ kò jẹ́ kí ó mọ ohun tí ì bá wí. Ìkùukùu kan bá ṣíji bò wọ́n, ohùn kan bá wá láti inú ìkùukùu náà tí ó wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”
Mak 9:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn. Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan ní ayé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu. Peteru sì wí fún Jesu pé, “Rabbi, ó dára fún wa láti máa gbé níhìn-ín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìbá sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ìkùùkuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”