Mak 9:1-32
Mak 9:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio tọ́ iku wò, titi nwọn o fi ri ti ijọba Ọlọrun yio fi de pẹlu agbara. Lẹhin ijọ mẹfa Jesu si mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, o si mu wọn lọ sori òke giga li apakan awọn nikan: ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn. Aṣọ rẹ̀ si di didán, o si funfun gidigidi; afọṣọ kan li aiye kò le fọ̀ aṣọ fún bi iru rẹ̀. Elijah pẹlu Mose si farahàn fun wọn: nwọn si mba Jesu sọ̀rọ. Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah. On kò sá mọ̀ eyi ti iba wi; nitori ẹ̀ru bà wọn gidigidi. Ikuku kan si wá, o ṣiji bò wọn; ohùn kan si ti inu ikuku na wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. Lojiji, nigbati nwọn si wò yika, nwọn ko si ri ẹnikan mọ́, bikoṣe Jesu nikan pẹlu ara wọn. Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, o paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun ti nwọn ri fun ẹnikan, bikoṣe igbati Ọmọ-enia ba ti jinde kuro ninu okú. Nwọn si fi ọ̀rọ na pamọ́ sinu ara wọn, nwọn si mbi ara wọn lẽre, kili ajinde kuro ninu okú iba jẹ. Nwọn si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Elijah ni yio tètekọ de? O si dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ, ni Elijah yio tètekọ, de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò; ati gẹgẹ bi a ti kọwe rẹ̀ nipa ti Ọmọ-enia pe, ko le ṣaima jìya ohun pipọ, ati pe a o si kọ̀ ọ silẹ. Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn si ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i, gẹgẹ bi a ti kọwe nipa rẹ̀. Nigbati nwọn si de ọdọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn ri ijọ enia pipọ lọdọ wọn, awọn akọwe si mbi wọn lẽre ọ̀ran. Lọgan nigbati gbogbo enia si ri i, ẹnu si yà wọn gidigidi, nwọn si sare tọ ọ nwọn nki i. O si bi awọn akọwe, wipe, Kili ẹnyin mbère lọwọ wọn? Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá; Nibikibi ti o ba gbé si mu u, a si ma nà a tantan: on a si ma yọ ifofó li ẹnu, a si ma pahin keke, a si ma daku; mo si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ki nwọn lé e jade; nwọn ko si le ṣe e. O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi. Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu. O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? O si wipe, Lati kekere ni. Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ. Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́. Lojukanna baba ọmọ na kigbe li ohùn rara, o si fi omije wipe, Oluwa, mo gbagbọ́; ràn aigbagbọ́ mi lọwọ. Nigbati Jesu si ri pe ijọ enia nsare wọjọ pọ̀, o ba ẹmi aimọ́ na wi, o wi fun u pe, Iwọ odi ati aditi ẹmi, mo paṣẹ fun ọ, jade lara rẹ̀, ki iwọ má ṣe wọ̀ inu rẹ̀ mọ́. On si kigbe soke, o si nà a tàntàn, o si jade lara rẹ̀: ọmọ na si dabi ẹniti o kú; tobẹ ti ọpọlọpọ fi wipe, O kú. Ṣugbọn Jesu mu u li ọwọ́, o si fà a soke; on si dide. Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade? O si wi fun wọn pe, Irú yi kò le ti ipa ohun kan jade, bikoṣe nipa adura ati àwẹ. Nwọn si ti ibẹ̀ kuro, nwọn si kọja larin Galili; on kò si fẹ ki ẹnikẹni mọ̀. Nitori o kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ nwọn o si pa a; lẹhin igbati a ba si pa a tan, yio jinde ni ijọ kẹta. Ṣugbọn ọ̀rọ na kò yé wọn, ẹ̀ru si ba wọn lati bi i lẽre.
Mak 9:1-32 Yoruba Bible (YCE)
Ó tún wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn kan wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun tí yóo dé pẹlu agbára.” Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọ sí orí òkè gíga kan, àwọn mẹta yìí nìkan ni ó mú lọ. Ìrísí rẹ̀ bá yipada lójú wọn. Ẹ̀wù rẹ̀ ń dán, ó funfun láúláú, kò sí alágbàfọ̀ kan ní ayé tí ó lè fọ aṣọ kí ó funfun tóbẹ́ẹ̀. Wọ́n rí Elija pẹlu Mose tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀. Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, ó dára tí a wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pàgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.” Ẹ̀rù tí ó bà wọ́n pupọ kò jẹ́ kí ó mọ ohun tí ì bá wí. Ìkùukùu kan bá ṣíji bò wọ́n, ohùn kan bá wá láti inú ìkùukùu náà tí ó wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” Lójijì, bí wọ́n ti wò yíká, wọn kò rí ẹnìkankan lọ́dọ̀ wọn mọ́, àfi Jesu nìkan. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, Jesu pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ròyìn ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí òun, Ọmọ-Eniyan, yóo fi jí dìde kúrò ninu òkú. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn nípa ìtumọ̀ jíjí dìde kúrò ninu òkú. Wọ́n bá bi í léèrè pé, “Kí ló dé tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́ dé?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Elija ni ó níláti kọ́ dé láti mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.” Ó wá bi wọ́n pé, “Báwo ni a ti ṣe kọ nípa Ọmọ-Eniyan pé ó níláti jìyà pupọ, kí a sì fi àbùkù kàn án?” Ó sì tún wí fún wọn pé, “Elija ti dé, wọ́n ti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ nípa rẹ̀.” Nígbà tí Jesu dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí ọpọlọpọ eniyan pẹlu àwọn amòfin, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn. Lẹsẹkẹsẹ bí gbogbo àwọn eniyan ti rí i, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá sáré lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i. Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀yin ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ń jiyàn lé lórí?” Ẹnìkan ninu wọn bá dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, ọmọ mi tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di odi ni mo mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ. Níbikíbi tí ó bá ti dé sí i, ẹ̀mí èṣù yìí á gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà yóo máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, yóo wa eyín pọ̀, ara rẹ̀ yóo wá le gbandi. Mo sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọn lé ẹ̀mí náà jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó? N óo ti fara dà á fun yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá.” Wọ́n bá mú un lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ẹ̀mí burúkú yìí rí Jesu, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yí nílẹ̀, ó ń yọ ìfòòfó lẹ́nu. Jesu wá bi baba ọmọ náà pé, “Ó ti tó ìgbà wo tí irú èyí ti ń ṣe é?” Baba rẹ̀ dáhùn pé, “Láti kékeré ni.” Ó ní, “Nígbà pupọ ẹ̀mí náà á gbé e sọ sinu iná tabi sinu omi, kí ó lè pa á. Ṣugbọn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkohun, ṣàánú wa kí o ràn wá lọ́wọ́.” Jesu wí fún un pé, “Ọ̀ràn bí èmi bá lè ṣe é kọ́ yìí, ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.” Lẹ́sẹ̀ kan náà baba ọmọ náà kígbe pé, “Mo gbàgbọ́; ràn mí lọ́wọ́ níbi tí igbagbọ mi kù kí ó tó.” Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ìjọ eniyan ń sáré bọ̀, ó bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó ní, “Ìwọ ẹ̀mí tí o jẹ́ kí ọmọ yìí ya odi, tí o sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò ninu rẹ̀, kí o má tún wọ inú rẹ̀ mọ́.” Ẹ̀mí náà bá kígbe, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó sì jáde. Ọmọ náà wá dàbí ẹni tí ó kú, tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan náà ń sọ pé ó ti kú. Ṣugbọn Jesu fà á lọ́wọ́, ó gbé e dìde, ọmọ náà bá nàró. Nígbà tí Jesu wọ inú ilé, tí ó ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí náà jáde?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Irú èyí kò ṣe é lé jáde, àfi pẹlu adura [ati ààwẹ̀.”] Láti ibẹ̀ wọ́n jáde lọ, wọ́n ń la Galili kọjá. Jesu kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, nítorí ó ń kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń wí fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́, wọn yóo pa á, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá ti pa á tán, yóo jí dìde lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.” Ṣugbọn ohun tí ó ń wí kò yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
Mak 9:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títí yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.” Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn. Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan ní ayé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu. Peteru sì wí fún Jesu pé, “Rabbi, ó dára fún wa láti máa gbé níhìn-ín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìbá sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ìkùùkuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!” Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkankan mọ́, bí kò ṣe Jesu nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú. Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí. Nísinsin yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin ń sọ wí pé, “Elijah ní yóò kọ́kọ́ dé.” Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Elijah yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Elijah ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.” Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹsẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́ òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn. Bí Jesu ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i. Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyànjiyàn?” Ọkùnrin kan láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́. Àti pé, nígbàkúgbà tí ó bá mú un, á gbé e ṣánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ eyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.” Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.” Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan náà ẹ̀mí náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lu ilẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófó lẹ́nu. Jesu béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?” Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.” Nígbàkúgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná àti sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́. “Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ” Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.” Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.” Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàntàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀: ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Hé è, ọmọ náà ti kú.” Ṣùgbọ́n Jesu fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dìde dúró. Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè níkọ̀kọ̀ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?” Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò ṣe nípa àdúrà.” Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Galili kọjá. Níbẹ̀ ni Jesu ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i. Nítorí ó kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí fun wọn pe, “A ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì pa á, lẹ́yìn ìgbà tí a bá sì pa á tan yóò jíǹde ní ọjọ́ kẹta.” Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà.