Mak 8:34-35
Mak 8:34-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si pè ijọ enia sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba fẹ tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi ati nitori ihinrere, on na ni yio gbà a là.
Mak 8:34-35 Yoruba Bible (YCE)
Ó pe àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti gbàgbé ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó wá máa tẹ̀lé mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
Mak 8:34-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn. Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là.