Mak 8:27-38

Mak 8:27-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

Jesu si jade, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ si awọn ileto Kesarea Filippi: o si bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre li ọna, ó wi fun wọn pe, Tali awọn enia nfi mi pè? Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti: ẹlomiran si wipe Elijah; ṣugbọn awọn ẹlomiran wipe, Ọkan ninu awọn woli. O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? Peteru si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na. O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ on fun ẹnikan. O si bẹ̀rẹ si ikọ́ wọn, pe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, a o si pa a, lẹhin ijọ mẹta yio si jinde. O si sọ ọ̀rọ na ni gbangba. Peteru si mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi. Ṣugbọn o yipada o si wò awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si ba Peteru wi, o ni, Kuro lẹhin mi, Satani: nitori iwọ ko ro ohun ti Ọlọrun bikoṣe ohun ti enia. O si pè ijọ enia sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba fẹ tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi ati nitori ihinrere, on na ni yio gbà a là. Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmi rẹ̀ nù? Tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmi rẹ̀? Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, ni iran panṣaga ati ẹlẹsẹ yi, on na pẹlu li Ọmọ-enia yio tiju rẹ̀, nigbati o ba de ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli mimọ́.

Mak 8:27-38 Yoruba Bible (YCE)

Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí àwọn abúlé tí ó wà lẹ́bàá ìlú Kesaria ti Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ ní ọ̀nà, ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan ń pè mí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ń pè ọ́ ní Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn ní Elija ni ọ́, àwọn mìíràn tún ní ọ̀kan ninu àwọn wolii ni ọ́.” Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́, ta ni ẹ̀yin ń pè mí?” Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.” Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn pé, “Ọmọ-Eniyan níláti jìyà pupọ. Àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin yóo ta á nù, wọn yóo sì pa á, ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.” Ó ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn kedere. Nígbà náà ni Peteru mú un, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí. Ṣugbọn Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá Peteru wí. Ó ní, “Kó ara rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ Satani. Ìwọ kò kó ohun ti Ọlọrun lékàn àfi ti ayé.” Ó pe àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti gbàgbé ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó wá máa tẹ̀lé mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Nítorí anfaani kí ni ó jẹ́ fún eniyan kí ó jèrè gbogbo dúkìá ayé yìí, ṣugbọn kí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Kí ni eniyan lè fi ṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú èmi ati ọ̀rọ̀ mi ní àkókò burúkú yìí, tí àwọn eniyan kò ka nǹkan Ọlọrun sí, Ọmọ-Eniyan yóo tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli mímọ́.”

Mak 8:27-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nísinsin yìí, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Galili. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Kesarea-Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Elijah tàbí àwọn wòlíì mìíràn ni ó tún padà wá sáyé.” Ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mí pè?” Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.” Ṣùgbọ́n Jesu kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde. Jesu bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Peteru pe Jesu sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí. Jesu yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Peteru pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Satani, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.” Nígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn. Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là. Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”