Mak 8:1-26
Mak 8:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọjọ wọnni nigbati ijọ enia pọ̀ gidigidi, ti nwọn ko si li onjẹ, Jesu pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ãnu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn kò si li ohun ti nwọn o jẹ: Bi emi ba si rán wọn lọ si ile wọn li ebi, ãrẹ̀ yio mu wọn li ọ̀na: nitori ninu wọn ti ọ̀na jijìn wá. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si da a lohùn wipe, Nibo li a ó gbé ti le fi akara tẹ́ awọn enia wọnyi lọrùn li aginjù yi? O si bi wọn lẽre, wipe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn si wipe, Meje. O si paṣẹ ki awọn enia joko ni ilẹ: o si mu iṣu akara meje na, o dupẹ, o bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; nwọn si gbé e kalẹ niwaju awọn enia. Nwọn si li ẹja kekeke diẹ: o si sure, o si ni ki a fi wọn siwaju wọn pẹlu. Nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ agbọ̀n meje. Awọn ti o jẹ ẹ to ìwọn ẹgbãji enia: o si rán wọn lọ. Lojukanna, o si wọ̀ ọkọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wá si apa ìha Dalmanuta. Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò. O si kẹdùn gidigidi ninu ọkàn rẹ̀, o si wipe, Ẽṣe ti iran yi fi nwá àmi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Ko si àmi ti a o fifun iran yi. O si fi wọn silẹ o si tún bọ sinu ọkọ̀ rekọja lọ si apa ekeji. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn. O si kìlọ fun wọn, wipe, Ẹ kiyesara, ki ẹ ma ṣọra nitori iwukara awọn Farisi ati iwukara Herodu. Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Nitoriti awa kò mu akara lọwọ ni. Nigbati Jesu si mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣàroye pe ẹnyin ko ni akara lọwọ? ẹnyin ko ti ikiyesi titi di isisiyi, ẹ ko si ti iwoye, ẹnyin si li ọkàn lile titi di isisiyi? Ẹnyin li oju ẹnyin kò si riran? ẹnyin li etí, ẹnyin kò si gbọran? ẹnyin kò si ranti? Nigbati mo bu iṣu akara marun larin ẹgbẹdọgbọn enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wi fun u pe, Mejila. Ati nigba iṣu akara meje larin ẹgbaji enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wipe, Meje. O si wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin? O si wá si Betsaida; nwọn si mu afọju kan wá sọdọ rẹ̀, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o fi ọwọ́ kàn a. O si mu afọju na li ọwọ́, o si fà a jade lọ sẹhin ilu; nigbati o si tutọ́ si i loju, ti o si gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, o bi i lẽre bi o ri ohunkohun. O si wòke, o si wipe, Mo ri awọn enia dabi igi, nwọn nrìn. Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba. O si rán a pada lọ si ile rẹ̀, wipe, Máṣe lọ si ilu, ki o má si sọ ọ fun ẹnikẹni ni ilu.
Mak 8:1-26 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ọpọlọpọ eniyan tún wà lọ́dọ̀ Jesu, tí wọn kò rí nǹkan jẹ, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà pẹlu mi, wọn kò ní ohun tí wọn yóo jẹ mọ́. Bí mo bá ní kí wọn túká lọ sí ilé wọn ní ebi, yóo rẹ̀ wọ́n lọ́nà, nítorí àwọn mìíràn ninu wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Níbo ni a óo ti rí ohun tí a óo fún gbogbo àwọn wọnyi jẹ ní aṣálẹ̀ yìí?” Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n ní, “Meje.” Ó bá pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó ní ilẹ̀. Ó mú burẹdi meje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n tún ní àwọn ẹja kéékèèké díẹ̀. Ó gbadura sí i, ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pín in fún àwọn eniyan. Àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó ẹ̀rúnrún àjẹkù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ ńlá meje. Àwọn eniyan tí wọn jẹun tó bí ẹgbaaji (4,000). Lẹ́yìn náà Jesu ní kí wọn túká. Lẹsẹkẹsẹ ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá lọ sí agbègbè Dalimanuta. Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n. Inú rẹ̀ bàjẹ́, ó ní, “Nítorí kí ni àwọn eniyan ṣe ń wá àmì lóde òní? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé a kò ní fún wọn ní àmì kan.” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó lọ sí òdìkejì òkun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbàgbé láti mú burẹdi lọ́wọ́ àfi ọ̀kan ṣoṣo tí wọn ní ninu ọkọ̀ ojú omi. Jesu bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò ní burẹdi ni.” Nígbà tí Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàrin ara yín pé nítorí ẹ kò ní burẹdi lọ́wọ́ ni? Ẹ kò ì tíì mọ̀ sibẹ, tabi òye kò ì tíì ye yín? Àṣé ọkàn yín le tóbẹ́ẹ̀? Ẹ ní ojú lásán ni, ẹ kò ríran? Ẹ ní etí lásán ni, ẹ kò fi gbọ́ràn? Ẹ kò ranti nígbà tí mo bu burẹdi marun-un fún ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan, agbọ̀n mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Mejila.” Ó tún bi wọ́n pé, “Nígbà tí mo fi burẹdi meje bọ́ àwọn ẹgbaaji (4,000) eniyan, agbọ̀n ńlá mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Meje.” Ó tún bi wọ́n pé, “Kò ì tíì ye yín sibẹ?” Wọ́n dé Bẹtisaida. Àwọn ẹnìkan mú afọ́jú kan wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó fọwọ́ kàn án. Ó bá fa afọ́jú náà lọ́wọ́ jáde lọ sí ẹ̀yìn abúlé, ó tutọ́ sí i lójú. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ o rí ohunkohun?” Ọkunrin náà ríran bàìbàì, ó ní, “Mo rí àwọn eniyan tí ń rìn, ṣugbọn bí igi ni wọ́n rí lójú mi.” Lẹ́yìn náà Jesu tún fi ọwọ́ kàn án lójú. Ọkunrin náà tẹjú mọ́ àwọn nǹkan tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ojú rẹ̀ sì bọ̀ sípò, ó wá rí gbogbo nǹkan kedere, títí kan ohun tí ó jìnnà. Jesu wí fún un pé, kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má ṣe wọ inú abúlé lọ.
Mak 8:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ. Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?” Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?” Wọ́n fèsì pé, “ìṣù àkàrà méje.” Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà. Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún. Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì (4,000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jesu wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dalmanuta. Àwọn Farisi tọ Jesu wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ́n béèrè fún ààmì láti ọ̀run. Jesu mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá ààmì? Lóòótọ́ ni mo sọ fún un yín kò si ààmì tí a ó fi fún ìran yín.” Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú àkàrà tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù àkàrà kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn. Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi àti ìwúkàrà Herodu.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrín ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni?” Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni. Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí? Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?” Wọ́n wí pé, “Méjìlá.” “Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì (4,000) pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?” Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.” Ó sì wí fún wọn pé, “Èéha ti ṣe tí kò fi yé yin?” Nígbà tí wọ́n dé Betisaida, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn. Jesu fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsin yìí?” Ọkùnrin náà wo àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.” Nígbà náà, Jesu tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere. Jesu sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹ́ni ní ìlú.”