Mak 7:5-8
Mak 7:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun? O dahùn o si wi fun wọn pe, Otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti ẹnyin agabagebe, bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia yi nfi ète wọn bọla fun mi, ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi. Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, ti nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ́. Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe.
Mak 7:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?” Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé, ‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi, asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí, ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí òfin Ọlọrun.’ “Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.”
Mak 7:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun.” Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé: “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi. Ìsìn wọn jẹ́ lásán, ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’ Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.”