Mak 7:1-30
Mak 7:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN Farisi si pejọ sọdọ rẹ̀, ati awọn kan ninu awọn akọwe ti nwọn ti Jerusalemu wá. Nigbati nwọn ri omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nfi ọwọ aimọ́ jẹun, eyini ni li aiwẹ̀ ọwọ́, nwọn mba wọn wijọ. Nitori awọn Farisi, ati gbogbo awọn Ju, bi nwọn ko ba wẹ̀ ọwọ́ wọn gidigidi, nwọn ki ijẹun, nitoriti nwọn npa ofin atọwọdọwọ awọn àgba mọ́. Nigbati nwọn ba si ti ọjà bọ̀, bi nwọn ko ba wẹ̀, nwọn ki ijẹun, ọ̀pọlọpọ ohun miran li o si wà, ti nwọn ti gbà lati mã fiyesi, bi fifọ ago, ati ikòko, ati ohunèlo idẹ, ati akete. Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun? O dahùn o si wi fun wọn pe, Otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti ẹnyin agabagebe, bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia yi nfi ète wọn bọla fun mi, ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi. Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, ti nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ́. Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́. Mose sá wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ; ati Ẹnikẹni ti o ba sọrọ baba tabi iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀ na: Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bi enia ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi, Korbani ni, eyini ni Ẹbùn, o bọ́. Bẹ̃li ẹnyin ko si jẹ ki o ṣe ohunkohun fun baba tabi iya rẹ̀ mọ́; Ẹnyin nfi ofin atọwọdọwọ ti nyin, ti ẹ fi le ilẹ, sọ ọ̀rọ Ọlọrun di asan; ati ọpọ iru nkan bẹ̃ li ẹnyin nṣe. Nigbati o si pè gbogbo awọn enia sọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ fi etí si mi olukuluku nyin, ẹ si kiyesi i: Kò si ohunkokun lati ode enia, ti o wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ti o le sọ ọ di alaimọ́: ṣugbọn nkan wọnni ti o ti inu rẹ̀ jade, awọn wọnni ni isọ enia di alaimọ́. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. Nigbati o si ti ọdọ awọn enia kuro wọ̀ inu ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre niti owe na. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye tobẹ̃? ẹnyin ko kuku kiyesi pe, ohunkohun ti o wọ̀ inu enia lati ode lọ, ko le sọni di alaimọ́; Nitoriti ko lọ sinu ọkàn rẹ̀, ṣugbọn sinu ara, a si yà a jade, a si gbá gbogbo onjẹ danù? O si wipe, Eyi ti o ti inu enia jade, eyini ni isọ enia di alaimọ́. Nitori lati inu, lati inu ọkàn enia ni iro buburu ti ijade wá, panṣaga, àgbere, ipania, Olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọ̀bia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwère: Lati inu wá ni gbogbo nkan buburu wọnyi ti ijade, nwọn a si sọ enia di alaimọ́. O si dide ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni, o si wọ̀ inu ile kan, ko si fẹ ki ẹnikẹni ki o mọ̀: ṣugbọn on kò le fi ara pamọ́. Nitori obinrin kan, ẹniti ọmọbinrin rẹ̀ kekere li ẹmi aimọ́ gburo rẹ̀, o wá, o si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀: Hellene si li obinrin na, Sirofenikia ni orilẹ-ède rẹ̀; o si bẹ̀ ẹ ki on iba lé ẹmi èṣu na jade lara ọmọbinrin rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Jẹ ki a kọ́ fi onjẹ tẹ awọn ọmọ lọrun na: nitoriti ko tọ́ lati mu onjẹ awọn ọmọ, ki a si fi i fun ajá. O si dahùn o si wi fun u pe, Bẹni Oluwa: ṣugbọn awọn ajá pãpã a ma jẹ ẹrún awọn ọmọ labẹ tabili. O si wi fun u pe, Nitori ọ̀rọ yi, mã lọ; ẹmi ẹ̀ṣu na ti jade kuro lara ọmọbinrin rẹ. Nigbati o si pada wá si ile rẹ̀, o ri pe ẹmi èṣu na ti jade, ọmọbinrin rẹ̀ si sùn lori akete.
Mak 7:1-30 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn Farisi ati àwọn amòfin kan tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu péjọ sí ọ̀dọ̀ Jesu. Wọ́n rí ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí ni pé, wọn kò wẹ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. (Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn. Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.) Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?” Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé, ‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi, asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí, ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí òfin Ọlọrun.’ “Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.” Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ. Nítorí Mose wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’ ati pé, ‘Kí á pa ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí baba tabi ìyá rẹ̀.’ Ṣugbọn ẹ̀yin wí pé, ‘Bí eniyan bá wí fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé ohunkohun tí n bá fun yín, Kobani ni,’ (èyí ni pé ẹ̀bùn fún Ọlọrun ni), ẹ ti gbà pé ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ohunkohun í ṣe fún baba tabi ìyá rẹ̀ mọ́. Ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ọpọlọpọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ tún ń ṣe.” Ó tún pe àwọn eniyan, ó ń wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ fi etí sílẹ̀, kí ọ̀rọ̀ mi ye yín. Kò sí ohun kan láti òde wá tí ó wọ inú eniyan lọ tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́. Ṣugbọn àwọn ohun tí ó ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. [ Ẹni tí ó bá ní etí láti gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”] Nígbà tí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, tí ó wọ inú ilé lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin náà kò ní òye? Kò ye yín pé kì í ṣe nǹkan tí ó bá wọ inú eniyan lọ níí sọ eniyan di aláìmọ́? Nítorí kì í wọ inú ọkàn lọ, bíkòṣe inú ikùn, a sì tún jáde.” (Báyìí ni ó pe gbogbo oúnjẹ ní mímọ́.) Ó tún fi kún un pé, “Àwọn nǹkan tí ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. Nítorí láti inú ọkàn eniyan ni ète burúkú ti ń jáde: ìṣekúṣe, olè jíjà, ìpànìyàn, àgbèrè, ojúkòkòrò, ìwà ìkà, ẹ̀tàn, ìwà wọ̀bìà, owú jíjẹ, ọ̀rọ̀ ìṣáátá, ìwà ìgbéraga, ìwà òmùgọ̀. Láti inú ni gbogbo àwọn nǹkan ibi wọnyi ti ń wá, àwọn ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.” Láti ibẹ̀ Jesu gbéra, ó lọ sí agbègbè ìlú Tire, ó sì wọ̀ sí ilé kan. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, ṣugbọn kò lè fi ara pamọ́. Obinrin kan tí ọdọmọbinrin rẹ̀ ní ẹ̀mí èṣù gbọ́ nípa rẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó wá kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ọmọ ìbílẹ̀ Giriki ni obinrin yìí, a bí i ní Fonike ní Siria. Ó ń bẹ̀ ẹ́ kí ó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọdọmọbinrin òun. Jesu wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ rí oúnjẹ jẹ yó ná, nítorí kò dára kí á mú oúnjẹ ọmọ kí á sọ ọ́ fún ajá.” Ṣugbọn obinrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, alàgbà, ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀rúnrún oúnjẹ àwọn ọmọ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili.” Jesu dá a lóhùn pé, “Nítorí gbolohun rẹ yìí, máa lọ sí ilé rẹ, ẹ̀mí èṣù náà ti jáde kúrò ninu ọmọ rẹ.” Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀, ó rí ọmọde náà tí ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, tí ẹ̀mí burúkú náà ti jáde kúrò lára rẹ̀.
Mak 7:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn Farisi sì péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé, tí ó wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́. (Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́. Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.) Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun.” Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé: “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi. Ìsìn wọn jẹ́ lásán, ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’ Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.” Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ. Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí ìyá rẹ̀ mọ́. Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.” Lẹ́yìn náà, Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín. Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.” Nígbà tí Jesu sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa. Jesu béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́? Nítorí tí kò lọ sínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n sínú ara, a sì yà á jáde, a sì gbá gbogbo oúnjẹ dànù.” (Nípa sísọ èyí, Jesu fihàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”) Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọ ni di aláìmọ́. Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọtaraẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.” Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri. Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun. Jesu sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.” Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ èérún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì.” “Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.” Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.