Mak 6:31-32
Mak 6:31-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Ẹ wá ẹnyin tikaranyin si ibi ijù li apakan, ki ẹ si simi diẹ: nitori ọ̀pọlọpọ li awọn ti nwá ti nwọn si nlọ, nwọn kò tilẹ ri ãye tobẹ̃ ti nwọn iba fi jẹun. Nwọn si ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù awọn nikan.
Pín
Kà Mak 6Mak 6:31-32 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá kí á lọ sí ibìkan níkọ̀kọ̀, níbi tí kò sí eniyan, kí ẹ sinmi díẹ̀.” Nítorí ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ń lọ, tí wọn ń bọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí àyè láti jẹun. Wọ́n bá bọ́ sinu ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n fẹ́ yọ́ lọ sí ibi tí kò sí eniyan.
Pín
Kà Mak 6Mak 6:31-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.” Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́.
Pín
Kà Mak 6